”Irọ́ ní pé àwọn ṣoja pá àwọn ògo wẹẹrẹ ní àríwá Naijiria”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria, Ọgagun Faruk Yahaya ti fi ọwọ osi da iwadii to ni awọn ikọ ọmọogun Naijiria n pa awọn ọmọde ni iha ariwa orilẹede Naijiria.

Oṣu Kejila, ọdun to kọja ni ileeṣẹ iroyin Reuters gbe iroyin jade pe awọn ikọ ọmọogun Naijiria to n tako ikọ agbesunmọmi Boko Haram ṣẹ oyun fun awọn ọdọbinrin ti awọn ikọ Boko Haram jigbe.

Iroyin naa lo mu ki ajọ iṣọkan agbaye kesi ijọba orilẹede Niajiria lati ṣewadii awọn ẹsun naa ni kiakia.

Ninu ọrọ rẹ, adari ikọ ọmọogun ilẹ ni Naijiria ni ikọ ọmọogun Naijiria pẹlu awọn ikọ ọmọogun to dara julọ ni agbaye.

Awọn ọmọogun Naijiria mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ, ti wọn si kawe gba oye bi o ṣe yẹ.

Awọn miran tilẹ ro pe ori igi la wa ni Niajiria amọ o yẹ ki o ye wọn pe awọn ikọ ọmọogun naa ti lọ gba imọ ni ilẹ okeere to fi mọ US ati UK, ti wọn si di ipo giga mu.

O ṣeni laanu pe a ko jamọ nkankan loju awọn ara ilẹ wa, ko si ohun ti a ṣe to dara loju wọn, eyi buru jai.

Bakan naa ni adari ikọ ọmọogun ile naa paṣẹ pe wọn gbọdọ ṣewadii ileeṣẹ iroyin Reuters naa ati idi ti wọn fi gbe iroyin ẹlẹjẹ nipa wọn.

Ọgagun Faruk Yahaya ni ko si otitọ̀ ninu iroyin naa ati pe awọn agbegbe ti wọn darukọ pe iṣẹlẹ naa ti waye kii ṣe ibi ti eniyan kan dede lọ, yoo nilo iwe aṣẹ lati kọja ni awọn agbegbe wọnyii.

Ìdí tí mo fi fi ẹjọ́ Obi, Datti sun DSS – Keyamo

Festus Keyamo, SAN.

Oríṣun àwòrán, festus keyamo

Minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ati ijafafa iṣẹ lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo, SAN ti fi ẹsun kan oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi ati igbakeji rẹ, Datti Baba-Ahmed pe wọn n gbiyanju lati ru awọn ololufẹ wọn soke lati da wahala silẹ lorilẹede Naijiria.

Nitori eyi, Keyamọ ti wa gba ileeṣẹ agbofinro DSS lọ bayii pẹlu iwe ifisun kan pe ki DSS o tete wa nnkan ṣe si ọrọ naa ko to di wi pe o burẹkẹ di ohun ti apa ko ni ka mọ.

Nigba to n farahan lori eto ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria, ‘Channels television’ Keyamo sọ wi pe oun fẹ ki DSS pe awọn mejeeji ni lori bi wọn ṣe n sọ kiri pe awọn ko ni gba kikede ti wọn kede Bọla Tinubu gẹgẹ bi aarẹ ti ilu dibo yan lorilẹede Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe esi idibo sipo aarẹ ti ajọ INEC fi sita fihan pe ipo kẹta ni LP duro si, Obi ati igbakeji rẹ ṣi n pariwo pe awọn lo bori idibo yii, ti wọn si n fọnrere rẹ pe oniruru iwa kotọ lo waye ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa bii iwa ifipakọluni, ati idunmọhuru mọni.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu igbakeji Peter Obi, Datti Ahmed ni ibo ẹgbẹ awọn le ni miliọnu mẹjọ ati pe oun mọ nnkan ti oun n sọ to si wa labẹ ofin.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn igun Tinubu ti ke sawọn to lulẹ nibi idibo naa lati gba ile ẹjọ lọ gẹ bi ofin ṣe laa kalẹ, eleyi ti awọn alatako ti foju wo pẹlu ifura.

Keyamọ ni nnkan ti awọn oludije ẹgbẹ oṣelu LP naa n ṣe ni lati ru awọn eeyan lọkan soke lati doju wọn kọ ẹka iṣedajọ.