Fídíò, Ọ̀dọ́mọdébìnrin tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi iṣẹ́ mọ́káliíkì, Duration 5,27

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ka nípa ”Baby Mechanic” ọ̀dọ́mọdébìnrin tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi iṣẹ́ mọ́káliíkì

Ọmọ ti yoo ba ya aṣamu, Yoruba ni lati kekere ni yoo ti ṣẹnu ṣamuṣamu.

Bẹẹ lọrọ ọdọmdebinrin yi jẹ eyi to mu dantọ nidi iṣẹ mọkaliliki.

Lasiko ti ọpọ awọn ẹgbẹ rẹ a maa ṣe ere iyepẹ tabi gun kẹkẹ kiri, idi iṣẹ mọkaliki ni Gloria Okotie wa.

Ọmọ ọdun mẹsan yi s pe baba oun loun maa n tẹle wa si ibiṣ ti oun si gba bẹ bẹrẹ si ni kọ nipa iṣ mọkaliki.

Gloria ni diẹ diẹ bi koun maa bawọn mu irinṣẹ, bi kini ọhun ṣe di nkan toun foju si niyẹn.

”Kii ṣe gbogbo ọjọ ni mo maa n tẹle wọn wa. Lopin ọsẹ nikan ni.”

Ifẹ ti Gloria ni si bi wọn ṣe n parọ epo ọkọ, tun ijanu ati awọn nkan mii ṣe lo mu foju si iṣẹ yi.

Adisọkan Gloris ni pe ko di onimọ nipa imọ ẹrọ baalu ofurufu.

Baba Gloria gab awọn Obi ati Alagbato nimoran lati gab ọmọ laaye lati kọ isẹto ba wu u ki wọn si se atileyin fun un bi o se yẹ.