Ṣé o tí gbọ́ nípa eNaira, owó àìrí tuntun tí CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀? Nkan tí ó ní láti mọ̀ rèé

Owo eNaira

Oríṣun àwòrán, NAirametrics

Banki apapọ Naijiria, CBN ti ṣe ifilọlẹ oju opo ayelujara itakun agbaye fun owo ori ayelujara eNaira.

Ọjọ Aje ni banki naa ṣe ifilọlẹ itakun agbaye naa, ṣaaju ọjọ kinni, oṣu Kẹwa ti wọn o ṣe ifilọlẹ owo tuntun naa ni gbangba.

Banki naa sọ pe owo yii yoo ṣe e ná lati ra nkan, gẹgẹ bi Naira ti a n na.

Banki CBN sọ pe eNaira yoo mu idagbasoke ba kara-kata ni abẹle ati nilẹ okeere, nitori pe eto sisan ati gbigba owo yoo dinwo, ti yoo si tun yára.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbesẹ naa waye lẹyin ti banki naa fi ofin de awọn owo ori ayelujara ‘Cryptocurrency’.

Iru owo wo ni eNaira?

Owo tuntun eNaira jẹ owó orí ayelujara lati ọdọ banki agba naa. Owo yii yoo jẹ nina gẹgẹ bi Naira onibeba.

Ki lo nii ṣe pẹlu apo asunwọn owo rẹ ni banki?

CBN sọ pe ikawọ oun ni eNaira yoo wa, ti awọn banki kekeeke yoo si ma a mojuto awọn owo ti o ba fi pamọ sọdọ wọn.

Wọn ni ipo kan naa ni eNaira yoo wa pẹlu Naira ti o le ri ni ojukoroju, ti o si le mu dani.

Wọn ni kii ṣe pe yoo rọpo owo ti a n na.

Amọ dipo lilọ si banki lati ṣi apo asunwọn, ori ayelujara App eNaira ti wọn pe orukọ rẹ ni “Speed”, ni wa a ti si apo asunwọn.

O si le lo App yii lori foonu rẹ bi ti awọn banki to n lo tẹlẹ.

Bakan naa, o le so asunwọn eNaira rẹ mọ apo asunwọn rẹ ni banki.