Àwọn ajínígbé ṣ’oró l’Eko, wọ́n jí Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith gbé

Ọgagun Sikiru Smith

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn ajinigbe ti tun soro nilu Eko pẹlu bi wọn ṣe ji ọgagun fẹyinti Sikiru Smith.

Adugbo Ajah nilu Eko ni wọn ti ji ibatan ọga agba ọlọpaa Musiliu Smith yi gbe lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ lati ọdo ileeṣẹ iroyin Naijiria The Punch,Smith n mojuto iṣẹ agbaṣe kan ni lasiko tawọn agbebọn ya bo ibudo iṣẹ naa.

A gbọ pe niṣe ni wọn bẹrẹ si ni yinbọnsoke ti wọn si ji Smith gbe salọ.

Inu ọkọ oju omi ti wọn gbe si itosi ni wọn gbe Smith si ti wọn si na papa bora.

Iroyin naa tẹsiwaju pe awakọ ọgagun yi lo ke gbajare pe wọn ti jin ọga oun gbe salọ.

Kọburu Odili ninu ọrọ to sọ ṣalaye pe awọn wa nibi tawọn ti n ṣiṣẹ ni ki awọn agbebọn yi to wa ji ọga rẹ gbe.

”awọn agbebọn yi dasọ boju wọn si bẹrẹ si ni yinbọn soke titi ti wọn fi ji ọga mi gbe salọ”

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko lori ọrọ yi, arakunrin Adekunle Ajisebutu sọ pe lootọ lawọn gbọ si iṣẹlẹ naa.

O ni iwadii n tẹsiwaju ati pe ọrọ ẹlẹgẹ ni iṣẹlẹ ijinigbe yi tori naa awọn ko fẹ sọ nkankan ti yoo ṣe akoba iwadii to n lọ lọwọ.

”Awọn ajinigbe ko ti sọ nkankan.Bi a ba tun mọ si nipa iṣẹlẹ yi, a o fi ọrọ naa to yin leti”