Ṣe lóòtọ́ ni pé àwọn obìnrin máa n lù ọkùnrin nínú ilé gẹ́gẹ́ bi olólùfẹ́?

Ṣe lóòtọ́ ni pé àwọn obìnrin máa n lù ọkùnrin nínú gẹ́gẹ́ bi olólùfẹ́

Oríṣun àwòrán, Others

Láìpẹ́ yìí ni onímọ̀ kan fi abájádé rẹ̀ síta lórí bi irú ǹkan ti àwọn ọkùnrin míràn ń fójú rọ́ nínú ìgbéyàwó wọn.

Onímọ̀ Ifeanyi Uzoamaka Chukwuma ti igbákeji olórí ilé ilé ẹkọ́ Fasiti Ibadan nígbà kan ri, ọ̀jọ̀gbọ́n Adeyinka Aderintọ, ti ẹ̀ka ìwà ọ̀daràn n salábójútó lo ṣagbejade iwadii yii.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìgbéyàwó ni wọ́n n fójú winá ìyà àjẹkúdorógbó nínú ìgbéyàwó wọ́n tí wọn kò si le sọ síta, nítorí àwujọ kò fi ààyè gba irú rẹ̀.

Àwujọ kò ni ìgbàgbọ pé ọkùnrin le máa kojú ìwà ipá nínú ìgbéyàwó wọn nítori wọn yoo máa fojú rẹ̀ wò wọ́n.

Nínú ìwádìí náà, Chukwuma jẹ ko di mímọ̀ pé, láàrìn àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó pọ̀ sí jùlọ ni Kosofe, Lagos Mainland, Agege, Mushin àti Ikorodu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nibe ni àwọn ọkùnrin tí n koju oníruurú ìwà ipá nínú ìgbéyàwó wọn.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìfìyàjẹni ní tí ìwà ipá fún ìbálòpọ̀, lílù àti fifi ìyà owó jẹni, ọdọ obinrin ni ariwo rẹ ti maa n jade.

Ó fi kun pé àwọn yi irú ǹka báyìí máa n ṣẹlẹ̀ si ni àwọn tí wọ́n bá dàgbà ju ìyàwó wọn lọ, wọ́n sábà máa n kojú ìwà ipá ju àwọn ti ìyàwó wọ́n jùlọ lọ.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, àwọn ọkùnrin tó bá jẹ́ pé kìí ṣe ìgbéyàwó àkọ́kọ́ wọ́n ni ṣe, ṣùgbọ́n àwọn tó ni ju ìyàwó kan lọ pẹ̀lú ni àǹfàni láti máa kojú ìgbáyàwó tó mú ipá dání.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olùwádìí náà fi kún pé, kò wá sí lábẹ́ àkóso bótiwù kórí, àwọn ọkùnrin yìí kìí sọ ǹkan ti ojú wọ́n ń ri nínú ìgbéyàwó tó mu ìpá dání.

“Ìdí ni pé, ẹ̀rù a maa bà wọ́n lórí ǹkan ti àwọn ènìyàn àwùjọ yóò sọ, ati pé, wọ́n sì n gbẹ́kẹ̀lé ìyàwó wọ́n láti gba owó àti àwọn ǹkan mírà ti wọ́n nílò”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ