Àwọn aláìsàn yóò máa san #1,000 lójúmọ̀ fún owó iná – Ilé ìwòsàn UCH, Ibadan

Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn University College Hospital, UCH, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ti ní àwọn aláìsàn tó bá wà ní ilé ìwòsàn náà yóò máa san ẹgbẹ̀rún kan náírà ní ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí owó iná.

Nínú ìwé àkọránṣẹ́ lábẹ́lé lọ́jọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní owó tó ń lé owó iná ọba àti bí dísù ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbẹ́nu sókè si ló mú àwọn pinnu láti ní kí àwọn aláìsàn máa san owó iná tí wọ́n bá lò.

 Ìwé náà tí alákoso ilé ìwòsàn náà, Wole Oyeyemi buwọ́lu lórúkọ gíwà àgbà ilé ìwòsàn ọ̀hún ní ìgbésẹ̀ yìí yóò jẹ́ kí àwọn le pèsè ìwòsàn tó péye fún àwọn aláìsàn.