Sé lóòtọ́ ní pé olólùfẹ́ méjì kú sínú mọ́tò Sienna nílùú Ìbàfò lẹ́yìn ìbálòpọ̀?

Oko Sienna

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin to gbode kan ni pe wọ́n ba oku ololufe meji ninu ọkọ̀ Sienna kan ni agbegbe Mowe – Ibafo ni ipinle Ogun.

Awọn ololufẹ ikọkọ meji kan la gbọ pe wọn ti ku sinu mọto lagbegbe NASFAT to wa niluu Mowe, ipinlẹ Ogun, ti awọn ọlọpaa si ti gbe oku wọn lọ si mọṣuari fun ayẹwo.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe lẹyin ti awọn mejeeji yii ba ara wọn laṣepọ tan ni wọn dagbere faye ninu mọto Toyota Sienna ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LSD 992 HH.

Iyẹn ni alẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, lagbegbe NASFAT to wa ni Mowe, opopona marosẹ ilu Eko si Ibadan.

Kini awọn ara adugbo sọ?

Nigba ti BC YORUBA de ibẹ̀, awọn to wa lagbegbe naa ti wọ́n ko fẹ́ ki a aruko wọ́n so pe awọn ri wọn lakooko ti wọn n ko ibasun fun ara wọn, ṣugbọn ti ko sẹni to sunmọ won.

Ọsan ana, ti i ṣe Tusidee, ọjọ Iṣẹgun lawọn eeyan yọju wo inu mọto naa, ti wọn si ba oku awọn mejeeji ninu mọto.

Awọn to ko firi oku awọn mejeeji yii ninu mọto ni wọn pariwo sita nitori oorun to ti n gba ile.

Leyin naa ni ero pe sibẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.

Lara wọn si lo gbe foonu lati ya fọnran kan to gba ori ayelujara kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Ileese olopaa ipinle Ogun sọ lori isẹ̀lẹ̀ naa?

Ṣugbọn nigba to n fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinle Ogun ṣalaye pe iroyin to jinna si otitọ ni awuyewuye ti awọn eeyan n gbe kaakiri lori iṣẹlẹ naa.

Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ sọ pe lotito ni ololufẹ meji ku sinu mọto ti wọn n sọ yii, ṣugbọn ki i ṣe ohun to sẹlẹ gangan ni wọn n gbe kiri.

Kini Oyeyemi ọ̀gá ọlọ́pàá sọ pé o selẹ̀ gangan?

Oyeyemi to je alukoro ileese ọlọ́pàá ipinlẹ̀ Ogun ti sọrọ̀ lori iselel naa bi iwadii se fihan.

O ni pe: “Ẹ jẹ ki n ṣalaye ohun to sẹlẹ fun un yin. Ṣe ẹ ri ọkunrin ati obinrin yẹn, awọn mejeeji jọ n fẹ ara wọn ni. Ọkunrin yẹn gba ile fun obinrin yii ni agbegbe kan niluu Eko.

“Ọkunrin yii lo lọ ba obinrin naa nile to gba fun un, ko ṣẹṣẹ maa lọ.

Mo ro pe ọrọ ṣebi ọrọ laaarin wọn.

Ibi ti wọn ti n fa ọrọ naa ni ọkunrin yii ti gbe nnkan, to si la mọ ọn lori, bo ṣe dakẹ niyẹn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbese wo ni awọn ara ilé Obinrin naa ti gbe ni agọ̀ ọ́lọ́paa ni Eko?

Oyeyemi salaye pe saaju ki fonran fidio naa to jade ni ọ̀rọ̀ yii ti waye ni Eko.

O ni pe: “Bi awọn ti awọn ara ile ololufe yii ti wọ́n jọ n gbe inu ile ṣe ri nnkan to sẹlẹ yii ni wọn ti gba teṣan ọlọpaa Ilajẹ nilu Eko lọ.

Ibe ni wọ́n si ti lọ ṣalaye fun awọn agbofinro ohun ti oju wọ́n ri.

Kini Okunrin ti wọ́n ri oku rẹ̀ yii se?

Ṣugbọn ni gbogbo asiko yii, ọkunrin yii ti gbe oku ọmọbinrin naa sinu mọto rẹ, to si salọ.

“Bo ṣe kuro nibẹ, ile rẹ lo gba lọ ni agbegbe Orimẹrunmu nitosi Ibafo, ipinlẹ Ogun nibi. Bo ṣe de ile lo kọ lẹta fun iyawo rẹ wi pe oun ti paayan, ki ẹnikẹni si ma ṣe wa oun, nitori oun ko mọ nnkan to le ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bawo ni okunrin naa se pa ara re?

Oyeyemi so pe: “Igba to kọ lẹta yii tan lo jade sita pada, to si lọ ra oogun apakokoro ti a mọ si Sniper nitosi NASFAT.

Ibẹ lo gbe ọkọ rẹ si, to fi mu oogun naa, toun naa si gbabẹ ku.

“Nigba ti awọn ọlọpaa maa debẹ, wọn ṣakiyesi pe awọn oku mejeeji yii ti n wu sinu mọto.

Ṣugbọn ohun ti awọn ti ko mọ nnkan to ṣẹlẹ n sọ ni pe lẹyin Ibalopọ lawọn mejeeji ku sinu mọto.

Rara ko ri bẹẹ.

Ẹjọ naa ti wa ni teṣan ọlọpaa Ilajẹ l’Ekoo.”