Àwọn Oníṣẹ̀ṣe l’Ọ́yọ̀ọ́ ń bèèrè àyájọ́ ìsìnmi láti sààmi ayẹyẹ ọjọ́ ìṣẹ̀ṣe

Onisese

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe, ẹka t’ipinlẹ Ọyọ ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ orileede Naijiria, paapaa ijọba ipinlẹ naa lati ya ọjọ kan sọtọ gẹgẹ bi ọlude lati saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ Iṣẹṣe agbaye.

Araba Olu Iṣẹṣe t’ilu Ibadan, Oloye Agba Ifalere Ọdẹgbemi Ọdẹgbọla lo sọ eyi l’ọjọ Aje, Mọnde, ana, ọjọ kedinlọgbọn, oṣu keji to ṣẹṣẹ pari yii, to si ni awọn n fẹ ki ijọba mọ riri ipa iṣẹṣe ninu idagbasoko ilu.

Ibi ayẹyẹ ọdun Ọṣẹ Meji Ọbamoro to waye ni gbọngan Mapo, to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni Oloye Ọdẹgbọla ti rawọ ẹbẹ naa sita.

Nibẹ lo ti dupẹ lọwọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde fun bo ṣe na ọwọ ifẹ ati ọrẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ oniṣẹṣe nipinlẹ naa.

Awon odiwọ́n wo lo lo lati fi sagbeyẹwo ibeere rẹ̀ nipa ọdun Isẹ̀se?

Nigba to n ṣe agbeyẹwo awọn ijọba tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ ati eyi ti asiko yii, o jẹ ko di mimọ pe ijọba Ṣeyi Makinde nikan lo ri ọrọ wọn ro, to si gba wọn laaye ninu awọn eto ati ilana rẹ.

O sọ pe ijọba Gomina Makinde nikan lo fi awọn Oniṣẹṣe sinu iṣakoso rẹ, lati fi mọ riri wọn, eyi to sọ pe yoo tubọ mu idagbasoke ba ipinlẹ naa, paapaa l’ẹka eto ọrọ aje.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Obamoro to je Oloye Odegboa salaye fun Gomina Makinde?

Nigba to n sọrọ lori pataki ayẹyẹ ọdun Ọsẹ Meji Ọbamoro, Oloye Ọdẹgbọla sọ pe ọjọ naa ni lati ṣe iranti ọjọ ti wọn da ilu Ibadan silẹ.

Bakan naa lo tun ṣalaye itan bi wọn ṣe tẹ ilu Ibadan do, ati bi Lagelu, ẹni to tẹ ilu naa do ṣe beere lọwọ Ifa (Ọsẹ Meji).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe; “Bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe n ka wa kun, ti wọn si n pe wa s’ibi akanṣe eto adura fawọn ẹlẹsin n’ipinlẹ Ọyọ,

ati awọn akanṣe eto pataki ti fi han pe Gomina Makinde ni igbagbọ ninu wa. O si ṣetan lati gba gbogbo awọn ẹlẹsin mọra lai ṣe ojusaaju.

“A si ti ni igbagbọ bayii pe gbogbo erongba wa, ati ẹdun ọkan wa lati beere fun ayajọ ọdun Iṣẹṣe yoo jẹ itẹwọgba labẹ ofin laipẹ

“Ki i ṣe asọdun wi pe a wa lẹyin Gomina digbi pẹlu ifọwọsowọpọ rẹ pẹlu wa, to si ti di ojuṣe wa lati ri i daju pe o pada s’ipo naa lẹẹkeji. Awọn eeyan wa ko ni i ja a kulẹ, paapaa to ba nilo adura wa.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini Esi Mogaji Fakayode Fayemi Fatunde to jẹ́ aarẹ́?

Bakan naa, akọwe ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe, Mọgaji (Ọmọwe) Fakayọde Fayẹmi Fatunde ati Aarẹ ajọ Ọsẹ Meji Ibadan, iyẹn Ose Meji Ibadan Foundation, Ifayẹmi Ifakayọde tun lo akoko naa lati rawọ ẹbẹ si gomina.

O ni: ti wọn si rọ ọ pe ko tubọ na ọwọ ifẹ naa siwaju si i, nipa fifi ọjọ kan silẹ gẹgẹ bi ọlude f’awọn oniṣẹṣe n’ipinlẹ Ọyọ.

Wọn ni eyi yoo tubọ jẹ ki ajọṣepọ to wa laaarin ẹgbẹ wọn ati ijọba tubọ gbilẹ si i, ti yoo si tubọ jẹ ki wọn bọwọ fun gomina ati ijọba rẹ ju ti tẹlẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu ọrọ tirẹ, kọmiṣanna fọrọ eto iroyin, aṣa ati irin ajo afẹ, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun jẹ ko di mimọ pe asiko ọtun ree fun gbogbo awọn oniṣẹṣe kaakiri ipinlẹ naa.

O toka si paapaa bi ijọba ṣe fi wọn si ipo pataki ninu iṣakoso, to si gba wọn lamọran lati ma ṣe dawọ ifẹ ati ifọwọsowọpọ wọn fun gomina ati ijọba ipinlẹ naa duro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bẹẹ lo gba wọn lamọran lati tubọ maa kọ awọn ọmọ wọn nipa iwa ọmọluabi, ki awọn naa si maa uwa ọmọluabi, eyi to lo ṣe pataki pupọ

“Gomina wa wa nibi ninu ẹmi. Gẹgẹ bi ẹyin naa ti ṣe fidi rẹ mulẹ pe gomina ti ṣe ohun ti awọn ijọba to ti kọja lọ ko ṣe nipa nina ọwọ ifẹ si i yin, akoko naa ree lati bẹrẹ si i polongo ipadabọ Gomina Ṣeyi Makinde lẹẹkeji.”