Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye márùn ún tí wọ́n ti ń wá l’Ogun

Ogun Cultist suspects

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti fi ṣikun ofin mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn tun jẹ adigunjale marun un niluu Ijebu Ode.

Ọlọpaa ni ilẹ ti ta si ti awọn ti n wa awọn afurasi naa lori oniruru ẹsun ki ọwọ to tẹ wọn lasiko ti wọn n mura lati ṣọṣẹ lopopona Molipa, ni Ijebu Ode.

Ọwọ tẹ awọn eeyan naa, Segun Olabiyi, ti apẹle rẹ n jẹ Koleje, Musa Atanda ti awọn tirẹ mọ si Musa SARS, Olorunjuedalo Adewale, Olamide Odewole ati Peter Anuoluwapo Akinyemi lẹyin ti awọn araalu kan ta ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Obalende, Ijebu Ode, lolobo.

Wọn mu awọn afurasi naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye lẹyin ile iturala De Prime lasiko ti wọn n gbimọ lati lọ ṣọṣẹ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi lede, o ni ni kete ti awọn afurasi naa kofiri awọn agbofinro ni wọn ṣina ibọn bolẹ, amọ ọwọ tẹ marun un ninu wọn, nigba ti awọn to ku na papa bora pẹlu oniruru ọta ibọn.

Lara awọn nnkan ti awọn ọlọpaa ri lara awọn afurasi naa ni ibọn agbelẹrọ, ọta ibọn ati oniruru oogun abẹnu gọngọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Atẹjade ọhun ni iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe awọn adigunjale naa lo ṣekupa ọlọpaa kan, Sgt Akeem Oseni, to n ṣiṣẹ ni Igbeba lẹnu iṣẹ rẹ.

Awọn afurasi ọhun sọ fun awọn ọlọpaa pe ìṣẹ wọn ni lati maa ge ọwọ ọtun awọn to ba ko si wọn lọwọ sọnu lẹyin ti wọn ba pa ifufẹ ẹni bẹẹ tan.

Wọn tun sọ fun ọlọpaa pe olori wọn, PERTH, jade laye lasiko ti wọn lọ digunjale.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti gboriyin fun akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa to mu awọn afurasi naa, o si ti paṣẹ ki wọn gbe ọrọ wọn lọ si ẹka ileeṣẹ ọhun to n ṣewadii iwa ọdaran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ