Àwọn ọmọ Naijiria tó wà ní Ukraine ké gbàjarè lórí ìdẹ́yẹsí tí wọ́n ń kojú lẹ́nu ibodè EU

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọ bibi ilẹ Afrika to n gbiyanju lati fi orilẹ-ede Ukraine silẹ ti ke gbajare lẹyin idẹyẹsi ti wọn n dojukọ lẹnu ibode ati wọ ilẹ EU.

Ọmọ Naijiria kan to n kẹkọọ nipa imọ iṣẹgun ni fasiti Kharkiv, Ruqqaya, sọ pe oun fẹsẹ rin fun wakati mọkanla lorumọju ki oun to de Medyka-Shehyni, to jẹ ibode Poland amọ wọn ko jẹ ki oun wọle.

O ni “Nigba ti mo de ibi yii, mo ri awọn alawọ dudu ti wọn n sun ni ita gbangba.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ko gba laaye lati wọ orilẹ-ede naa nitori wọn ni awọn ọmọ ilẹ Ukraine ni yoo kọkọ wọle, amọ ko le sọ boya ọmọ orilẹ-ede Poland ni awọn aṣọbode naa tabi ti Ukraine.

O ni oun ri ti wọn faye gba ẹgbẹlẹgbẹ awọn alawọ funfun lati wọle lẹnu ibode naa, ṣugbọn iwọmba perete awọn ọmọ ilẹ Afrika ni wọn jẹ ko wọle.

Ruqqaya n gbiyanju lati de Warsaw nibi ti yoo wọ baluu ti yoo gbe pada wa si Naijiria.

Ni ti alawọ dudu miran, Isaac, to de ẹnubode Medyka ni aago mẹrin abọ idaji, o ni awọn aṣọbode sọ fun oun pe awọn ọmọ orilẹ-ede Turkey ni yoo kọkọ wọle, ko to kan awọn ọmọ bibi ilẹ Afrika.

Awọn eeyan miran tun sọ fun BBC pe awọn ti ha si ẹnubode Przemyśl nitori awọn aṣobode ilẹ Ukraine ko gba awọn laye lati kọja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Timothy to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọọ Naijiria ni Lyviv ni ohun ti oju awọn n ri ni awọn ẹnubode naa kii ṣe keremi, ati pe iyawọ wa laarin bi wọn ṣe n ṣe si awọn ọmọ Ukraine ati awọn to jẹ alawọ dudu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Segun, to jẹ akẹkọọ ni Kyiv ni oun ko le lọ si ẹnubode nitori iwe irinna oun wa lọwọ awọn to ba oun to paali oun de orilẹ-ede naa.

Ẹwẹ, ọọfisi ijọba Naijiria ni Poland ti sọ pe oun ti ko awọn oṣiṣẹ kan lọ si ẹnubode naa lati ṣeranwọ fun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rekọja lati Ukraine si Poland.