Osinbajo tí kò yojú síbi ìpolongo ìdìbò kò ba ǹkankan jẹ́- APC Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko ti sọrọ lori bi igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo ko ṣe yọju sibi ipolongo idibo sipo aarẹ to n lọ lọwọ ni Naijiria.

APC ni aiyọju igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo  sibi ipolongo oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ko ni ki oludije ma wọle ninu idibo gbogboogbo to n bọ losu to n bọ.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Seyi Oladejọ lo sọ eyi lasiko to n sọrọ lori idi ti Osinbajo ko ṣe yọju sibi ipolongo ọhun.

Oladejo ni aisi Osinbajo nibi ipolongo naa ko da awọn duro lati ṣe aṣeyọri ninu idibo to n bọ naa.

Ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn to gbangba sun lọyẹ, ati pe alakala ti wa lati ṣiṣẹ karakara fun aṣeyọri idibo naa.

Ìdí nìyìí tí Osinbajo kò ṣe yojú síbi ìpolongo oludiboìdìbò sípò ààrẹ Tinubu- Festus Keyamo

Ninu ọrọ rẹ,  agbẹnusọ fun ipolongo idibo sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC (pcc), Festus Keyamo ti sọrọ lori idi ti Osinbajo ko ṣe si ni ipolongo ti wọn ti ṣe ni awọn ipinlẹ kọọkan.

Keyamo ni aarẹ Buhari lo paṣẹ fun Osinbajo lati maṣe lọ si ibi ipolongo idibo nitori a ti boju to ọrọ ilu.

O ni Osinbajo lo n bojuto awọn eto iṣejọba lọwọ ni ko ṣe ri aaye yọju sibi ipolongo naa.

Amọ awọn onwoye ni kani Osinbajo wọle gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ lati dije du ipo aarẹ ni idibo abẹle ẹgbẹ ni yoo yoju si ibi ipolongo naa.

Ẹgbẹ oṣelu naa ni o da awọn loju pe idibo naa yoo ṣe eṣe.