Afenifere ní kí olùdíje gbájúmọ́ ohun tí wọ́n ní fárá ìlú lásìkò ìpolongo ìbò dípò èébú

Bola Tinubu, Atiku Abubakar ati Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Bí ètò ìdìbò gbogbogboò níbi tí àwọn ọmọ Nàìjíríà yóò ti tún máa yan àwọn adarí tuntun tí yóò tukọ̀ orílẹ̀ èdè yìí àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan fún ọdún mẹ́rin mìíràn, ẹgbẹ́ Afenifere ti kọminú lórí bí ìwà ìpáǹle ṣe ń gbilẹ̀ níbi ètò ìpolongo ìbò láàárín àwọn olóṣèlú.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Afenifere, Jare Ajayi fi léde lọ́jọ́ Àìkú, Afenifere ní àwọn nǹkan tí àwọn olùdíje fẹ́ ṣe fún ará ìlú ló yẹ kí wọ́n gbájúmọ́ níbi àwọn ètò ìpolongo ìbò wọn dípò títàbùkù ara ẹni.

Afenifere ní ìpèníjà tó ń kojú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí kọjá kí àwọn olùdíje kan máa tahùn síra wọn lásìkò tó yẹ kí wọ́n fi máa sọ ohun gbòógì tí wọ́n ní fún ìlú lọ.

Èèkàn ẹgbẹ́ ilẹ̀ Yorùbá yìí ní lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn olùdíje kàn ń sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn ni tí wọ́n bá dé òde láti polongo ìbò àti pé ìgbésẹ̀ yìí ti ń fa ìjà láàárín àwọn olólùfẹ́ wọn.

Wọ́n ní níbi tí òṣèlú Nàìjíríà dé dúró lónìí, kò yẹ kí àwọn olóṣèlú pàápàá àwọn tó ń wá ipò kan tàbí òmíràn ṣì wà ní ìpele tó jẹ́ wí pé èébú ni wọ́n ń bu ara wọn dípò kí wọ́n máa sọ ohun táwọn ara ìlú fẹ́ gbọ́.

Ajayi nínú àtẹ̀jáde náà fi kun pé àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí àwọn olúdíje àti àwọn agbẹnusọ wọn ń sọ sí ara wọn ń fún àwọn alátìlẹyìn wọn ní ìgboyà láti máa ṣèkọlù síra wọn èyí tó le fa ìtàjẹ̀sílẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé onírúurú àwọn fídíò tó ń ṣàfihàn ìwà ipá tí àwọn ènìyàn ń wù síra ló ti ń gbòde lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí tó sì ní òpin gbọ́dọ̀ débá àwọn ìwà yìí tí ìdìbò gbogbogboò yóò bá lọ ní ìrọ̀wọ́rọsẹ̀.

Nígbà tó ń fi ìkọnilóminú rẹ̀ hàn lórí àwọn ìwà ìpáǹle yìí pẹ̀lú gbogbo ìwé àdéhùn àláfíà tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yìí tọwọ́bọ̀ pó kò ní sí làásìgbò lásìkò ìbò, Ajayi ní ìwádìí fi hàn pé kò dí ní ọmọ Nàìjíríà mẹ́t[padínlọ́gbọ̀n tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ láàsìgbò òṣèlú lọ́dún 2022 nìkan.

Bákan náà ló fi kun pé olùbádámọ̀ràn ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ètò ààbò, Babagana Monguno náà fìdí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ìkọlù méjìléláàdọ́ta láàárín àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ló wáyé láàárín oṣù kan péré ìyẹn láàárín oṣù Kẹwàá sí oṣù Kọkànlá ọdún tó kọjá.

Afenifere wá pàrọwà sí àwọn olùdíje àtàwọn olóṣèlú láti jìnà síwà bóòba o pá, kí wọ́n gbájúmọ́ ètò tí wọ́n ní fún ìlú láti tán ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn ọmọ Nàìjíríà fínra.