Israel/Gaza: Ẹ jọ̀wọ́ ogun sílẹ̀ kí ọmọ mi le wálé

Aworan Hersh Goldberg-Polins

Oríṣun àwòrán, Others

Iya ọkan lara ọmọ orilẹede Israel-Amẹrika to wa ni ahamọ ni Gaza sọ fun BBC pe o ṣeeṣe koko ki Hamas ati Israel tọwọ iwe adehun lori pe wọn yoo juwọ silẹ, ti wọn yoo si tun awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ.

Herch Goldberg-Polins, ẹni to ṣe ọjọbi ọdun mẹtalelogun ni oku ọjọ mẹrin ti wọn yoo jigbe ni bi ayẹyẹ Nova lọjọ keje oṣu kẹwaa, ni wọn ri ninu fọnran awọn eeyan to wa ni ahamọ eyi ti wọn fi lede lọsẹ to kọja.

Iya Hersh ni ibanujẹ lo jẹ nigba ti oun ri fọnran naa.

“Bi mo ṣe gbọ ohun ọmọ mi, mo bẹrẹ si ni sukun nitori n ko ti gbọ ohun rẹ lati bi oṣu mẹfa.

“Pe o si n rin, ti mo si ri pe alaafia lo wa, emi ati baba rẹ bu sẹkun , ti mo si ni lati di ọkan mi mu.”

“N ko ti ẹ mọ ohun ti mo n sọ. Mo kan n pariwo, ti mo si n sukun, Jon, baba rẹ naa n sukun.”

Hersh Goldberg-Polin wa ni bi ayẹyẹ orin Nova ni agbegbe kan to sumọ Gaza nigba ti awọn agbebọn Hamas kọlu agbegbe naa, ti wọn si ṣekupa eeyan to le ni ẹgbẹrun kan, ti wọn si tun mu awọn lẹẹru.

O le ni eeyan 360 ti wọn pa nibi ayẹyẹ orin naa.

Hersh gbiyanju lati kuro ni agbegbe naa pẹlu awọn yooku sugbọn ọwọ ikọ agbebọn pada tẹ.

Ko to di pe wọn ri ninu fọnran, igbakẹyin ti wọn ri gbẹyin ni igba ti wọn gbe sinu ọkọ ikọ Hamas, ti apa kan si ti di awati.

Sugbọn ninu fọnran to sẹsẹ jade lati ọwọ ikọ Hamas, Hersh gbe apa rẹ soke lati fihan kamẹra sugbọn o ni apa ni bẹ.

O bu ẹnu atẹlu ileeṣẹ ologun Israel in Gaza ko to wa ba awọn obi rẹ ati awọn aburo obinrin sọrọ, to si rọ wọn pe ki wọn jawọ lọrọ rẹ lati gba itusilẹ.

“Apa ọwọ rẹ jẹ ohun ibẹru fun wa,” Iya salaye.

Hersh ni igbagbọ wa pe ko le si lara awọn eeyan to ṣeeṣe ki wọn gba itusilẹ ni saa eeyan to fẹ gba itusilẹ ti adehun ba waye.

Pupọ awọn ti yoo gba itusilẹ ni awọn obinrin ati arugbo sigbọn o ṣeeṣe pe ki awọn eeyan to farapa naa pẹlu awọn ti yoo gba itusilẹ.

“Mo ni igbagbọ. Mo n gba adura pe igbeṣẹ ti wọn fẹ gbe jẹ ti yoo fopin gbogbo rogbodiyan yii.”