Fídíò, ‘Ẹ̀rú bà mí lọ́jọ́ tí mo wọ bọ́ọ̀sì dẹ́rẹ́bà ọlọ́wọ́ kan lọ Ilorin’, ìrírí àwọn èrò ọkọ̀ rèé, Duration 7,55

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Babatunde Ayanniyi One hand driver: Kí ni mo fẹ́ dà láyé mọ́ báyií bí wọ́n ṣe gé ọwọ́ mi ló gba ọ̀kàn mi

Ṣé bí ọlọwọ kan ba pero si ọkọ tan tẹẹ ri pe oun ni yoo wa ọkọ naa lọ ibi ti n lọ, ki ni yoo wa sọkan yin?

Babatunde Ayanniyi kii ṣe aimọ fun oloko awọn awakọ agbegbe rẹ rara ni ilu Ibadan tori oun funrarẹ rẹ awakọ ni amọ ọwọ kan pere lo n lo fi wa ọkọ.

Babatunde Ayanniyi

BBC Yoruba ba awakọ yii rinrinajo lati ibi kan si omiran lati lee fiimu bi o ṣe n fi ọwọ kan ṣoṣo wa ọkọ.

Iṣẹlẹ to fa sababi bo ṣe padanu ọwọ rẹ kan jẹ aburu gbaa eyi to ṣẹlẹ ni ọdun bii mọkanla sẹyin ninu ijamba ọkọ nla kan loju popo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bi Ayanniyi ṣe wa n ṣe e to fi ọwọ kan to ku wa ọkọ ko yeni to boya ninu irọrun ni tabi ninu irora. Ko si ẹni ti yoo ri i ti ko ni ya lẹnu.

“Ọlọwọ meji gan n wa ọkọ, Ọlọrun lo n ba eeyan wa a”. O ni “èrò pé kí mo fẹ́ dà láyé mọ́ báyií bí wọ́n ṣe gé ọwọ́ mi”.

Iṣẹ awakọ yii lo ti n ṣe ko to kan agbako ijamba pẹlu bo si ṣe la iriri ijamba ati pipadanu ọwọ kan to, o tun pada sẹnu iṣẹ ọkọ kan naa.

Babatunde n na ilu Ogbomoso si Ibadan to fi mọ ilu Ilorin.

Awakọ ọlọwọ kan

“Igba ti awọn eeyan mi wo o wipe ọwọ yii n jẹra nibi ti wọn kọkọ gbe mi lọ ni wọn ṣe tun gbe mi lọ si ile iwosan UCH”.

Babatunde ni: mo bomije loju nigba ti wọn sọ fun mi pe wọn yoo ge apa mi ni”.

O sọ fun BBC pe oun n bọ lati ipinlẹ Katsina ni ijamba buruku yii ṣẹlẹ titi to fi ni lati tọwọ bọwe pẹlu awọn mii to kangun si i. O tọwọ bọwe, wọn si fi iṣẹ abẹ ge ọwọ naa.