Ooni ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ̀bùn tuntun ta Olorì Naomi lọ́rẹ tán ní, ìfẹ́ wọn dúró, kò sí ìpínyà- Aàfin Oòdúà

Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi – Ojaja II

Amọṣa aafin Ọọni nilu Ile Ifẹ tii ṣe ile Oodua ti sọ pe kosi ohun to jọọ rara.

Kabiyesi Ọọni lọwọ ti a n sọrọ ṣi n sọ pe oun ṣi ni ọkọ Olori Ṣilẹkunọla, ko si si oun kan to n jẹ ipinya laarin awọn mejeeji.

Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun Kabiyesi Ọọni Adeyẹye Ogunwusi, Oloye Moses Ọlafare ba BBC News Yoruba sọ, o ni bi gbogbo eeyan ṣe ri atẹjade naa lori ayelujara ni Kabiyesi ati aafin ile Oodua naa ṣe rii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ati pe titi di bi a ṣe n sọrọ yii igbesẹ naa ṣajeji si aafin Ọọni ati itẹ Ooni funrarẹ.

Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi – Ojaja II

Oloye Ọlafare ni eyi ko sọ pe ko lee si awọn ipenija kọọkan laarin wọn o, nitori ko si igbeyawo ti kii ni ipenija tirẹ.

“Ipinya ninu igbeyawo kii ṣe ohun ti eeyan n gbe jade lori ayelujara. Ko si nnkan to n jẹ ipinya laarin wọn”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agbẹnusọ fun Ọọni Ogunwusi ṣalaye pe titi alẹ ọjọru to ṣaaju Ọjọbọ ti atẹjade naa jade loju opo ayelujara Olori Ṣilẹkunọla, kabiyesi ati olori rẹ ṣi wa papọ ti wọn jọ ṣere.

Koda, Olafare ni ọjọru ni kabiyesi fi ẹbun nla yunyun kan taa lọrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aafin Oodua ni bi a ba n sọrọ ikọsilẹ ninu igbeyawo, ati ọkọ, ati iyawo lo maa jumọ fi ọwọ si pe awọn fẹ pinya Ko si ohun, kii ṣe lilọ polongo lori ayelujara ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ