Ẹ fura àwọn agbésùmọ̀mi láti Mali fẹ́ wọ ìlú Abuja

Ero

Oríṣun àwòrán, @Others

Awọn agbésùmọ̀mi lati Mali ń gbèrò láti wọ àwọn ààlà Nàìjíríà láti kọlu olú-ìlú Abuja, awọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ìwọlé àti ìjáde lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe titaniji fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn.

Ile-iṣẹ tó ń rí sí ìwọlé àti ìjáde lorilẹ-ede Naijiria ti fi awọn oṣiṣẹ ijọba rẹ si oriṣiriṣi awọn ibudo aala kaakiri orilẹ-ede yìí itaniji láti dènà ikọlu àwọn agbésùmọ̀mi sí oluilu orilẹede Nàìjíríà Abuja.

Lẹta naa ti wọn kọ ranṣẹ ni ọjọ ketalelogun, Oṣu kejila, ọdun 2021, pẹlu akole rẹ,

‘Awọn agbésùmọ̀mi fẹ ṣe ikọlu si Abuja’ ti Alakoso ikọ tó ń mójú to aala orilẹ, Edirin Okoto, sì fowo si ni orukọ Adele ọga àgbà ajọ alábòójútó ìjáde àti ìwọlé ni Nàìjíríà Idris Jere.

Iwe naa ti wọn kọ ranṣẹ ni wọ́n fi ranṣẹ si gbogbo awọn alaṣẹ aladani ati awọn ọlọpa aala ni gbogbo orilẹ-ede Nàìjíríà.

Lara awon ti won wa ni Seme, Idi Iroko, Jibia, aala Illela pelu awon osise mìíràn to wa ni papakọ ofurufu Murtala Mohammad, papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, papakọ ofurufu Mallam Aminu Kano, láàrin awon miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ka, báyìí pé. “Láti ọfiisi ti Ag CGI lẹyin ifiweranṣẹ to ni pajawiri lati ọdọ Alakoso (OSGF).

Àwọn kan ń gbiyanju lati ṣe ikọlu si Ilu Abuja tí ṣe Olu-ilu Naijiria, laarin ọjọ ti kẹtala ati ọjọ kọkanlelogbọn, Oṣu kejila, ọdun 2021.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ikọlu tí wọ́n ń pinnu naa ni wọn sọ pe o jẹ eyi ti oludari DRAHMANE ń pinnu. OULD ALI, aka Mohammed Ould Sidat, ọmọ orilẹ-ede Algeria pẹ̀lú l iranlọwọ. Zahid Aminon, ọmọ orilẹ-ede Niger kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ijabọ naa tọka sì pe awọn mejeeji naa n bọ wa si Nigeria lati Mali tí wọ́n yoo si gba Gan ati Niger Republic kọja pẹlu tọkọ Toyota Hilux funfun kan tó ní àkọsílẹ̀ idanimọ AG157EKY.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn fi kún wipe awọn meji wọnyi ni awọn ẹlẹgbẹ mẹ́rin mìíràn ni Naijiria ti wọn ti wa nilẹ lati ra wọn lọwọ.

“O tun ni pe Ali gba iwe irinna Algerian pẹlu orukọ Najim Ould Ibrahim.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ