Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo

Alaafin's First Wife

Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one

Kii ṣe ohun aṣiri pe Eledua fi ọpọ aya kẹ Kabiesi, Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi.

Amọ ayaba Abibat Nihinlola Adeyemi ni aya rẹ akọkọ, awọn mejeji si ti wa gẹgẹ bii tọkọ-taya lati nnkan bii ọgọta ọdun titi di asiko yii.

Iya Adodo, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe olori naa kii kan n ṣe aya Alaafin lasan, oun ni ẹni ti ọpọ awọn to sun mọ ori Ade naa mọ gẹgẹ bii igi lẹyin ọgba Kabiesi.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Alaafin ni atilẹyin olori naa to bẹẹ to fi jẹ pe oun lo gba Alaafin nimọran lati fẹ iyawo tuntun.

Lonii, iyawo Alaafin ti le ni mẹwaa.

Iroyin ni Alaafin gbe ayaba Abibat niyawo lasiko ti olori naa wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun lẹyin ti awọn mejeji pade nipasẹ aburo Alaafin to jẹ akẹgbẹ ayaba nile ẹkọ kan naa lọdun 1956.

Alaafin's First Wife

Oríṣun àwòrán, Iwo odidere

Iyẹn ṣaaju ki Alaafin ti gori itẹ awọn baba rẹ lọdun 1970.

O tẹlẹ Alaafin lọ silu Eko nibi to ti ṣiṣẹ diẹ, o tun kọ iṣẹ ranṣo-ranṣọ, ti Ọlọrun si fi ọmọ mẹta ta awọn mejeji lọrẹ.

Gbogbo awọn ọmọ ti ayaba naa bi fun Kabiesi lẹyin awọn mẹta naa ni wọn ti dagba bayii, wọn si yan, wọn yanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ ori kan naa ni ayaba Abibat ati Alaafin Oyo, ṣugbọn kii ṣe oṣu kan ni wọn bi wọn.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 1938 ni wọn bi ayaba Abibat.

Alaafin's First Wife

Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one

Wọn si bi si idile Laguna, ni adugbo Agunpopo, niluu Oyo.

Ayaba yii kan naa lo bi ọmọ okunrin ati obinrin akọkọ ti Ọlọrun fi ta Alaafin lọrẹ.

Adura wa ni pe ki Ọlọrunnlọra Kabiesi ati Ayaba Abibat Adeyemi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ