Ọdún Sango máa tó rí ìbuwọ́lù àjọ àgbáyé láìpẹ́ – Makinde

Makinde àti àwọn onisango

Oríṣun àwòrán, Paula Gomez

Ayẹyẹ Sango agbaye to maa n waye ni ilu Oyo ni o ṣeeṣe ki ohun naa gba ontẹ ajọ agbaye to n ri si aṣa ati Iṣẹṣe lagbaaye gẹgẹ bii ti ayajọ Ọsun Osogbo.

Eyi ni ariwoye Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde nibi ayẹyẹ ọdun Sango ni agbaye eyi to waye ni Aafin Alaafin ilu Oyo.

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni ohun ti buwọlu abadofin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa gbe siwaju oun fun ibuwọlu lati sọ gbogbo ogunjọ oṣu Kẹjọ di ọjọ isinmi lati ṣajọyọ ọjọ Iṣẹṣe nilẹ Yoruba.

Kọmiṣọna fun Aṣa ati Igbafẹ ipinlẹ Oyo, Wasiu Olatunbosun to ṣoju gomina nibi ayẹyẹ ọdun Sango naa lo fọrọ naa lede lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ nibi ayẹyẹ naa.

Awọn alejo to wa kopa nibi ayẹyẹ ọdun Sango
Awọn alejo to wa kopa nibi ayẹyẹ ọdun Sango

Luiza Ponciano, ọkan lara awọn oyinbo orilẹ ede Brazil to wa sibi ayẹyẹ ọhun ṣalaye wi pe gbogbo ohun ti o ṣoju ohun ninu ayẹyẹ ọdun yii ya oun lẹnu pupọ.

Ponciano ni bi o tilẹ jẹ wi pe ọmọ bibi ilu Brazil ni oun, oun fẹran nipa aṣa ati iṣe Yoruba nitori naa ni oun si fi wa kopa nibi ayẹyẹ naa lati ni imọ kikun nipa aṣa Yoruba si.

“Aṣa Yoruba dara pupọ, ko ba dára tí awọn aṣa yii lọ ba n tẹsiwaju, ọpọlọpọ awa ara Brazil lọ feran ede ati aṣa yoruba”

Ẹlomiran ti oun naa tun sọrọ, Everson Ribeiro ṣalaye wi pe igba akọkọ ti oun yoo ma wa si orilẹ-ede Naijiria niyi to si ni oun ni igbagbọ pe oun ṣi maa tun pada wa ti awọn to ba n gbe aṣa larugẹ bii ti ọdun Sango ba tun waye.

Lara awọn to dara nibi ayẹyẹ naa ni ẹgbẹ Igunnu ti ilu Iseyin, Sango ilu Iseyin, Sango Oyo, Egungun Danafojura ati awọn ẹgbẹ oṣere miran.

Ayẹyẹ Sango agbaye yii ni o jẹ ayẹyẹ Sango agbaye keji ti yoo waye lẹyin ti Kabiyesi Alaafin ti ilu Oyo, Alaafin Adeyemi waja ni ọdun 2022.

Awọn alejo to wa kopa nibi ayẹyẹ ọdun Sango
Awọn alejo to wa kopa nibi ayẹyẹ ọdun Sango

Ọ̀pọ̀ èrò péjọ ní Ọ̀yo láti ṣe ayẹyẹ Ọdún Sàngó ní àgbáyé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez

Asekagba ayeye ọdun Sango Agbaye ti ọdun yii yoo waye lonii ninu gbagede aafin Alaafin ti Ọyọ lonii ọjọ kọkàndínlógún oṣu kẹjọ, odun yii.

Ayeye ajọdun sango agbaye jẹ ajọdun ti o maa n waye lọ́dọọdún ti awọn ẹlẹsin Iṣẹṣe ati awọn ọmọ Yoruba maa n ṣe fun orisa Sango.

Oriṣa Sango ni Yoruba gbagbo wi pe o ni agbara lati pe ina ati ara jade, ti wọn tun ṣe apejuwe rẹ bi jagunjagun ti o ṣi jẹ ọba kẹta ti Ilu Ọyọ.

Ayeye naa lo ti bẹrẹ lati ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun yii nibiti,oriṣiriṣi eto bii,Ogun ajobo,Sango Koso,ayẹyẹ ọdun Oya,Ọdun Ọsun,Ọdun Ajagba ti oni yoo si jẹ ayẹyẹ ti yoo kadi rẹ nilẹ.

Awọn aworan lati ibi ọdun Sango naa ree…

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez

Aworan

Oríṣun àwòrán, Paul Gomez