Ka nípa nkán tí Iyabo Ojo àti àwọn èèkàn amúlúdùn sọ lórí ‘sex tape’ Tiwa Savage

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tiwa Savage

Ninu ọrọ tawọn eeyan n mu bẹnu loju opo ayelujara ni Naijiria, oke tente leleyi to ni ṣe pẹlu fidio ibalopo Tiwa Savage to lu sita wa.

Ọkẹ aimọye awọneeyan lo n wa fidio naa bi ẹni n wa owo ti awọn si n sọ iriwisi ọtọọtọ nipa rẹ.

Laipẹ yi ni akọrin takasufẹ naa pariwo sita pe eeyan kan fẹ fi fọnran yi gba owo lọwọ oun to si niboun ko ba san owo oun yoo lu sita.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Fidio naa ti wa lu sita bayi ti awọn gbajumọ ori ayelujara ati awọn mii si ti n sọ ero wn nipa rẹ.

Die ree ninu awọn to da si ọrọ yi ati nkan ti wn ni lati sọ.

Iyabo Ojo-Ko si ẹni ti ko lẹru lẹbọ, ko si giri

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba Iyabo Ojo wa lara awọn to ni ki Tiwa Savage ma ṣe foya lori fidio naa to lu sita.

Loju opo rẹ ni Instagram@iyaboojofespris, niṣe lo fi fidio orin Tiwa Savage kan sibẹ to si ni ko si ẹni ti kii gbẹsẹ, ki Tiwa Savage maa bori lọ.

Ọrọ yi to ko ko pọ ṣugbọn labẹ rẹ awọn eeyan mii naa tun da si ti ọp n fi atilẹyin wn han si Tiwa Savage pe ko ma ṣe foya.

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage

Fun apẹrẹ, @am_tolufatokiladega n beere pe kini Tiwa Savage ṣe to buru?O ni igboya rẹ lati koju ẹni to fẹ fi fidio naa gba owo lọwọ rẹ jẹ iwuri.

O ni bi Tiwa Savage ko ba kọ lati san owo fun ẹni naa ni, ki ba ma gbadun owo mẹnumọ to fẹ gba lori nkan to ṣe.

Asiko to yẹ ki ẹyin ololufẹ Tiwa fi ifẹ han ree Daddy Freeze

Ilumọọka sọrọsọrọ Daddy Freeze ti dari ọrọ sọdọ awọn to pe ara wọn lololufẹ Tiwa Savage

Gbajugbaja sọrọsọrọ yi niasiko tawn obinrin yoo gbaruku ti ara wọn lo de yi

Oríṣun àwòrán, Daddy Freeze

“Nkan to ṣe,gbogbo eeyan lo n ṣe.Iyatọ to wa ni pe o kan gbe kamẹra lọ sibẹ ni.”

O ṣalaye pe ‘fọnran ibalopọ’ rẹ yi yoo tabuku awọn obinrin ni ko si ni da ko ribẹ

O fi kun pe asiko rẹ kawọn obinrin gbaruku ti kan lara wọn ki wn si sinmi lati maa fi ṣe yẹyẹ.

“Ẹni tẹ n wo fi ṣe awokọṣe ree,aayo yin tabi ki lorukọ tẹ n pe.Asiko lo de yi lati gbaruku ti,”

”Ko nilo owo yintabi nkan mii,ifẹ lo nilo ki fi han an.”

Oṣere Nollywood nii,Susan Peters naa da si ọrọ yi

Susan Peters

Oríṣun àwòrán, Instagram/Susan Peters

Loju opo r ni Instagram, niṣe lo beere pe ki lo de ti eeyan yoo fiya fidio obinrin ti ko ni fi oju ara rẹ si.

“Ki lo de ti wa tiẹ fi lọ ya fnran fidio gan alara?

O fi kun pe ”Ohun kohun to ba ṣe,wa gbẹsan rẹ…gboingboin la wa lẹyin rẹ”

Susan Peters

Oríṣun àwòrán, Instagram/Susan Peters

Ọrọ ti Mercy Aigbe naa sọ ko fi taratara yatọ si eleyi ti Iyabo Ojo sọ.

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mercy Aigbe

Ninu fnran fidio kan ti oun ṣe oṣerebinrin Gorgina Onuoha sọ pe ”ọkunrin to ba nifẹ r ko ni ya fidio ibalopọ yin”

O gba awọn obinrin lamọran pe ki wọn ma ṣe fi gbogbo ọkan tan ọkunrin toun ti bi ifẹ ba ṣe n pa wn bi ọti to.

“Ma fi ọkan tan eeyan tan, koda to fi mọ ọkọ rẹ.”

Kini Tiwa Savage s nipa fidio yi?

Ninu ọrọ to fi sita loju opo ayelujara, o ni awọn to wa nidi ki wọn ba orukọ oun jẹ pẹlu fidio naa n binu oun tori pe oun fi ọr naa ṣe awada loju agbo.

O ni pẹlu boun ti ṣe logun sita lori fidio naa, oun ti ribi ka wn lọwọ ko.

Laiko to n kọrin loju agbo, Tiwa sọ pe ko ni si ni ti yoo ri fọnran fidio yi amọ o jọ pe awọn to n halẹ mọ ti pada fi sita faraye.