Fídíò, Wo ajá yìí tóo lè fi “Remote” rán níṣẹ́ tàbí rí ojú olè tó ń rí, ìpínlẹ̀ Ondo ló wà, Duration 7,54

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“To ba fi le ri eeyan tabi to gbọ ohun, awọn to ṣee ti ko iṣẹ sii lori pe ko bẹrẹ si ni gbo eeyan tabi nkan naa”.

Aja agbelẹrọ yii jẹ akanṣe iṣẹ a’sekagba ikawe awọn ọmọ ile ẹkọ fasiti Adekunle Ajasin mẹta kan ti ṣaadede ti gbajugbaja bayii lẹyin ti aworan iṣẹ ọwọ wọn jade sori ayelujara ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni pin in kaakiri.

Aja Agbelẹrọ

Oríṣun àwòrán, Adeyi Stephen

Ọmọ ile ẹkọ fasiti Akugba ni ipinlẹ Ondo ni awọn mẹtẹta – Aiyegbeni John Osoke, Charles Olalekan, ati Adeyi Stephen, wọn jọ korajọ lati jọ ṣeto, po eelo rẹ wọn si jọ ‘se aja idaabobo naa jade.

Lara ohun pataki ti wọ́n se fun iwulo Aja yii nipe wọn ṣe ẹrọ ilewọ oludairi ti oloyinbo n pe ni “Remote:” lati lee dari rẹ ko maa gbo tabi ṣe ohun to ba wu olowo rẹ.

Awọn ọmọ fasiti to ṣe Aja Agbelẹrọ

Oríṣun àwòrán, Adeyi Stephen

Olukọ wọn ni fasiti ni oun ri awọn akẹkọọ mẹtẹta gẹgẹ bi akinkanju to gbọ ẹkọ daadaa ni oun ṣe fi oye awọn nkankan han wọn lati le da nkan ṣe funra wọn ti wọn si fakọyọ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, awọn ọmọ ile ẹkọ fasiti naa sọ ohun to sun wọn kẹrẹkẹrẹ de bẹ.

Gẹgẹ bi wọ́n ṣe sọ ọ, iṣẹ akanṣe Aja yii le mu ojutuu de ba iṣoro ati ipenija aabo lai fibẹẹ jẹ ki eniyan da sii pupọ ju bii kika fidio, gbigbọ ariwo tabi pipariwo. Bakan naa, wọn ṣalaye fun BBC awọn ipenija ti wọn koju lasiko ti wọn n ṣe iṣẹ akanṣe aṣekagba fasiti yii.