Ìjọba Nàìjíríà gbẹ́sẹ̀ lé iléeṣẹ́ bàlúù Dana Air

Aworan minisita irinna ofurufu, Festus Keayamọ ati balu Dana to yọ kuro loju opo lọjọ Iṣẹgun

Oríṣun àwòrán, NCAA/others

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ni ki ileeṣẹ irinna ofurufu Dana Air lọ rọọkun nile titi di igba ti iwadi pa pari lori ijafafa iṣẹ rẹ lẹka irinna ofurufu lorilẹede Naijiria.

Aṣẹ yii n waye lẹyin ti ọkan lara awọn baluu ileeṣẹ Dana yọ kuro loju opo papakọ ofurufu ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa nilu Eko lọjọ Iṣẹgun.

Minisita fun eto irinna ofurufu lorilẹede Naijiria, Festus Keyamo lo fi iwe aṣẹ naa ranṣẹ si ajọ to n ṣe amojuto igbokegbodo ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria, NCAA.

Minisita Keyamo ṣalaye ninu iwe naa pe igbesẹ yii ṣe pataki lọna ati lee mojuto ifẹsẹmulẹ ati titẹle awọn ofin ati ilana antẹle gbogbo to yẹ fun irin ajo ofurufu.

“Pẹlu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, ati bi alaafia ati abo awọn arinrinajo ṣe ṣe pataki si, minista ti paṣẹ pe ki ẹ paṣẹ fun ileeṣẹ irinna ofurufu Dana lẹyẹ o ṣọka titi di igba titi di igba ti iwadi to kuna ba waye.”

Iwe aṣẹ lọ rọọkun nile ti wọn fun Dana Air

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Minisita fun irinna ofurufu ni Naijiria ṣalaye pe iṣẹlẹ to waye si baluu Dana to yọ kuro loju opo baluu lọjọ Iṣẹgun tubọ tọka si bi ọrọ naa ṣe ṣe pataki si, ati pataki igbesẹ kiakia lati daabo bo gbogbo awọn ti ọrọ kan.

Iṣẹlẹ to waye lọjọ Iṣẹgun mu ki ajọ to n ṣakoso papakọ ofurufu ni Naijiria, FAAN o ti oju opo 18L/36R ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed to wa nilu Eko pa ti ko si baluu kankan to gba oju opo naa fo tabi balẹ.

Ọjọru ni wọn to ṣi ojo opo baluu naa pada lẹyin ti wọn ti gbe baluu naa kuro nibẹ.