Ìgbìmọ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ lórí #ENDSARS ti parí ìṣẹ́, àbọ̀ rèé

EndSARS Panel Lagos

Oríṣun àwòrán, The Focus

Igbimọ ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu gbe kalẹ lati ṣe iwadii awọn ẹsun ifiyajẹni ti araalu fi kan awọn ọlọpaa SARS, ti pari isẹ rẹ.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni gomina Sanwo-olu gbe igbimọ naa kalẹ lati gbọ ọrọ lẹ́nu awọn to kagbako ìjìyà lọwọ awọn ọlọpaa SARS ti ijọba tuka lasiko naa.

Sugbọn, wọn tun fi iwadii iṣẹlẹ to waye ni Lekki Tollgate ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, kún isẹ igbimọ ọhun.

Onidajọ Doris Okuwobi to jẹ alaga igbimọ naa sọ pe ₦410 miliọnu ni awọn fi san owo itunu fun olùpẹ̀jọ́ 71 ti ọlọpaa da lóró.

Onidajọ Okuwobi sọ pe iwe ẹsun 255 ni igbimọ naa gba lati ọwọ araalu, 252 yẹ fun igbẹjọ, sugbọn 182 ni wọn gbọ ẹjọ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ṣalaye pe igbimọ naa ko ri aaye gbọ ẹsun 52. O ni sugbọn, awọn yoo ko awọn ẹsun ti wọn o raaye gbọ naa papọ mọ àbọ̀ ti wọn fẹ ẹ gbe fun ijọba ipinlẹ Eko, ati imọran nipa igbesẹ to ba yẹ lori wọn.

O rọ awọn ti wọn ko gbọ ẹsun wọn tabi ti wọn ko pari lati má bẹru.

Onidajọ Okuwobi sọ pe o ṣe e ṣe ki ijọba ipinlẹ Eko da igbimọ kan silẹ, ti yoo ma a gbọ ẹsun títẹ ẹtọ ọmọniyan, eyi to tun le gbọ ẹsun wọn.

Lori iwadii ti igbimọ naa ṣe lori iṣẹlẹ ‘ipaniyan’ to waye ni Lekki Tollgate ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, Onidajọ Okuwobi sọ pe awọn pari iwadii lori iṣẹlẹ naa, ọwọ wọn si tẹ awọn ẹri kan.

O ni to ba jẹ pe lootọ ni awọn eeyan kan kagbako nibi iṣẹlẹ naa, ara awọn nkan ti igbimọ naa yoo sọ fun ijọba ni pe ki wọn o san owo itunu fun wọn.

Bẹẹni ko ni yọ awọn ọlọpaa to kagbako nibi rogbodiyan to waye lasiko iṣẹlẹ ENDSARS, silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Botilẹjẹ pe ẹnikan lara awọn agbẹjọro awọn oluwọde ENDSARS bẹ igbimọ naa lati ka àbọ̀ iwadii rẹ lori iṣẹlẹ Lekki Tollgate ni gbangba, Onidajọ Okuwobi sọ pe awọn ko le ṣe bẹẹ, nitori pe ofin National Economic Council (NEC) to gbe igbimọ naa ro sọ pe ijọba ni wọn gbọdọ gbe abajade iwadii wọn fun.

O sọ pe awọn yoo gbe àbọ̀ iwadii meji fun ijọba ipinlẹ Eko, nipasẹ ileesẹ eto idajọ.

Àwọn àbọ̀ naa da lori iṣẹlẹ Lekki Tollgate, ati ikeji lori bi awọn olopaa ṣe fi iya jẹ araalu, paapaa àwọn olopaa SARS ti ijọba tuka.