Nkán mẹ́rin tó yẹ kóo mọ̀ nípa àjọ̀dún Maolud Nabiyy tàwọn Mùsùlùmí ń ṣé

Muslim faithful celebrate di end of di Ramadan fasting

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti fi ikini ranṣẹ si awọn musulumi orileede naa lori ajọdun ọjọ ibi Anọbi Muhammad (SAW).

Kaakiri agbaye lawọn musulumi n kopa ninu ajọdun ti wọn fi n ṣe iranti ọjọ ti wọn bi Anọbi yi.

Ninu atẹjade to fi sita, o ni oun fi akoko yi gba awọn musulumi niyanju lati ”wa afirijin ki wọn si samulo ẹkọ ati igbe aye Anobi (SAW)

Ṣaaju ni ijọba Naijiria ti kede ọjọ Kọkandilogun oṣu Kẹwa gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Ọjọ yi ṣe deede ọjọ Kejila oṣu Rabi’al-awwal ti awọn musulumi Sunni kan a maa fi ṣe ayajọ yi.

Ni tawọn Shia,ọjọ Kẹtadinlogun oṣu yi kanna ni wn ya sọtọ.

Nkan mẹrin to yẹ ko mọ nipa ayajọ yi

Eid-el-Kabir

Oríṣun àwòrán, MUHAMMADU BUHARI FILE

Ibi ti ayajọ yi ti ṣẹwa

Wọn ya ọjọ yi sọtọ lati maa fi ṣe iranti ọjọ ibi Anọbi Muhammad(SAW)

Ko si akọsilẹ pato ọjọ ti wọn bi Anọbi gangan ti eyi si mu ki awọn musulumi maa mu ọjọ ọtọọtọ.

Lede larubawa Maolud tunmọ si ọjọ ti wọn bi eeyan to si j pe nilu Makkah ni orileede to n jẹ Saudi Arabia ni wọn ti bi Anọbi ni ọdun 570AD

Leyi tii jẹ ododo Anọbi ko ṣe ayajọ ọjọ ibi rẹ nigba to wa laye koda awọn to sunmọ ni Sahabee ko ṣe ajọdun yi.

Ni asiko awọn Abbasids lẹyin iku rẹ lawọn kan kọkọ bẹrẹ ajọdun yi ti awọn miran si ni lasiko awọn Fatimid ni wọn sọ di ajọdun ti olori ilu gaan fọwọ si.

Awọn orileede wo lo n kopa ninu ajọdun yi?

Ko fẹẹ si orileede musulumi tabi orileede tawọn musulumi pọ si ti wọn o ti maa ṣe ajọdun yi.

Ethiopia, India, UK, Turkey, Nigeria, Sri Lanka, France, Germany, Italy, Iraq, Iran, Maldives, Morocco, Jordan, Libya, Russia ati Canada wa lara wọn.

Amọ ṣa ni orileede Qatar ati Saudi wọn kii ṣe ajọdun yi bẹẹ si ni wọn o ya ọjọ sọtọ fun toripe wọn ka kun eewọ.

Ki lo rọ mọ ajọdun yi?

Aworan awon okunrin musulumi

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn musulumi gbe Anọbi si ipo ọla ati ẹyẹ ṣugbọn kii ṣe gbogbo wọn lo gba pe o yẹ ki wọn fi ayajọ Maolud yẹ si.

Idi ti wọn fi sọ bẹ nipe ko si ninu akọsilẹ ofin Islam bẹẹ si ni Anọbi ko pa awọn musulumi laṣẹ lati ṣe .

Fun awọn to maa n ṣe ayajọ yi, wọn a maa ṣe ile wọn lọjọ ti wọn wọn a si maa pinnkan jijẹ ati mimu lasiko yi.

Pupọ maa n pin ounjẹ lati fi ṣe itọrẹ tawọn mii a si maa ka orin ewi nipa Anọbi si eti igbọ awọn ọmọ wọn

Awọn ti kii ṣe ayajọ yi gba pe o da ki eeyan maa gba awẹ lọjọ Aje nitori Anọbi naa a maa ṣebẹ ni iranti ọjọ ti wọn bi saye.

Fakinfa lori ọrọ yi

Ọrọ yi jẹ eleyi to n ja rainrain laarin awọn musulumi paapa awọn to gbagbọ pe ko yẹ ki wọn ṣe afikun nkan ti Anọbi ko ṣe ninu ẹsin.

Fawọn to n ṣe wn ni nitori ifẹ ati apọnle tawọn ni si Anọbi lawọn fi n ṣe ayajọ yi.

Ninu alaye wọn, wọn ni wọn a maa ṣe ayẹsi ni tiko to Anọbitori naa o y ki awọn ṣe iranti ati apọnle pẹlu ayajọ yi

Gẹgẹ bi awọn Kristẹni kọọkan ti kii bawọn ṣe ajọdun Keresi nitori Jesu ko pawọn laṣẹ rẹ, awọn musulumi kan paapa awọn to n ṣe isọjipada Sunnah Anọbi, Ahlul Sunnah ni afikun bayi tako ilana ẹsin Islaamu.