Fídíò, Ojú mi fọ́ àmọ mi ò rí ara mi gẹ́gẹ́ bí oníbárà ni mo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ gboyè tí mo di lẹ́kíṣọ́rà orí ayélujára – Sanya Adegbaye, Duration 6,34

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sanya Adegbaye blind Yoruba teacher: Torí kí ojú mi lè là ni gbogbo owó Kòkó bàbá mi run sí

Ọgbẹni Sanya Adegbaye jẹ eeyan to ni ipenija oju ti ko lee riran amọ ti awọn aṣeyọri rẹ laye ti jẹ ohun iwuri fun ọpọlọpọ.

Jijẹ akanda eeyan ti ko lee fi oju riran ko di Sanya lọwọ rara lati tẹsiwaju nile aye rẹ.

Ọgbẹni Sanya ti kẹkọọ gboye ninu imọ ede Yoruba bayii to si tun ti goke di olukọ ede Yoruba to dantọ lori ayelujara.

Sanya sọ fun BBC Yoruba pé ohun to ba le mu oun ka iwe de ile ẹkọ giga fasiti, oun mọ pe ibi kan ṣi wa ti oun n lọ to ju ibi to wa bayii lọ.

Sanya onipenija oju

“Kii ṣe pe wọn bi mi lai loju, mo riran, mo si n lọ ile ẹkọ ti awọn to loju naa n lọ amọ mo mọ pe lati kekere ni mo maa n lo awọ oju ti mo si maa n lọ ile iwosan kaakiri..

Ọmọbibi ilu Ile Ife yii ni lẹyin ti awọn gbiyanju titi koda to fi dori adura lo jẹ ki oun ati idele rẹ gbe igbesẹ ti ko ni jẹ ko di onibara to n tọrọ jẹ lọjọ iwaju.

Eyi lo mu ki o ṣe idanwo lati wọ ile iwe giga fasiti Obafemi Awolowo to si ri i wọ bo tilẹ jẹ pe o mẹnu ba ọpọlọpọ ipenija to koju.

Sanya woye pe “diẹ ọmọkunrin ko to”, lo ṣe tun tẹra mọ oniruuru iṣẹ to le ṣe lati la laye lai gbe igba agbe ṣiṣe bi awọn eeyan ṣe maa n reti ki awọn afọju ṣe.