Fídíò, Lójú ayé mi, n kò gbàgbọ́ pé a le ra búrẹ́dì ní N800 àbí N1000, ẹ dìbò fún PDP – Olumide aderinokun, Duration 7,51

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olumide Aderinokun: Ẹ̀jẹ̀ Obasanjo sì wà ní PDP, gbágbá ló wà lẹ́yìn mi

Olumide Aderinoku tíí ṣe olùdíje sílé aṣòfin àgbà fẹ́gbẹ́ PDP ní Ogun Central bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí àfojúnsùn rẹ̀ fún aráàlú, tí wọn bá dìbò fun.

Olumide Aderinoku tíí ṣe olùdíje sílé aṣòfin àgbà fẹ́gbẹ́ PDP ní Ogun Central ti bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí àfojúnsùn rẹ̀ fún aráàlú, tí wọn bá dìbò fun.

Gẹgẹ bi oludije naa se wi, ilu ti le pupọ ju laye isejọba APC, ti oun ko si nigbagbọ pe gbogbo eroja le wn to bayii.

“Lójú ayé mi, n kò gbàgbọ́ pé a le ra búrẹ́dì ní N800 àbí N1000”

Aderinoku ni birikila ni oun, ti oun si n ba awọn onisẹ ọwọ miran sisẹ papọ eyi to mu ki oun sun mawọn eeyan to wa ni ẹsẹ kuku lati mọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ́.

Oludije sipo asofin agba naa wa sọrọ nipa ajọsepọ rẹ pẹlu aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oluseguun Obasanjọ, Ibikunle Amosun ati idi to se n dije naa.

Bakan naa lo tun foju tẹmbẹlu isejọba gomina APC ni Ogun, Dapo Abiodun eyi to ni o mẹhẹ pupọ.