Paa Kwesi Asare láti Ghana ni akọ̀ròyìn tó gba àmì ẹ̀yẹ BBC News Komla Dumor Award ti ọdún 2023

Aworan

Agbohunsafẹfẹ lori ẹrọ amohunmaworan ni Ghana, Paa Kwesi Asare ti gba ami ẹyẹ BBC News Komla Dumor Award, ti ọdun 2023.

Asare to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni ẹni kẹjọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa.

Paa Kwesi Asare ni adari ẹka royin eto ọrọ aje nileeṣẹ iroyin TV3, nibi to ti wa fun ọdun meje.

Ami ẹyẹ BBC News Komla Dumor Award wa fun iranti akọroyin BBC, Komla Dumor to dede ṣalaisi ni ẹni ọdun mọkanlelogoji lọdun 2014.

O ṣiṣẹ takunktakun lai se imẹlẹ nigba aye rẹ lati rii pe iroyin to munadoko nipa ilẹ Afrika jade si gbogbo aye.

Awọn adajọ naa ti wọn fun ni ami ẹyẹ naa ni Asare jẹ onimọ ẹkunrẹrẹ nipa iṣẹ akọroyin to si n ṣalaye awọn ọrọ to le kọkọ ni ọna to rọrun fun awọn araalu lati ni oye rẹ.

Komla Dumor

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu ọrọ rẹ, Asare ni idunnu ati ayọ lo jẹ fun oun bi oun ṣe gba ami ẹyẹ naa, ti oun yoo si sa ipa oun lati ri pe ami ẹyẹ naa mu igbega ba iṣẹ ti oun yan laayo naa.

Arakunrin naa ni yoo lo Osu mẹta ni olu ileeṣẹ BBC to wa ni ilu London nni ẹka amohunmaworan, redio ati lori ẹrọ ayelujara.

Bakan naa ni yoo ma gbe eto ẹkọ lọwọ awọn akọroyin to datọ ni ileeṣẹ BBC , ti wọn yoo si maa tọ si ọna.

Gẹgẹ bi ẹni to gba ami ẹyẹ yii, yoo lọ si orilẹede kan ni ilẹ Afrika lati ṣe kọ iroyin nipa wọn, eleyii ti wọn yoo fi si ori ẹrọ ayelujara BBC fun igbohunsafẹfẹ.

‘’Inu mi dun lati gba ami ẹyẹ BBC News Komla Dumor Award.’’

Ko si akọroyin ti ko fẹ lati gba iru ami ẹyẹ yii, Komla ni iwalaye rẹ jẹ akọroyin ti gbogbo aye fẹran ti ẹmi naa si fẹran gẹgẹ bi awokọṣe mi.

Awọn miran to ti gba ami ẹyẹ naa ri ni Dingindaba Jonah Buyoya, Victoria Rubadiri, Solomon Serwanjja, Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure and Nancy Kacungira.