Èmi ni dẹ́rẹ́bà ọ̀kọ̀, àwọn ọmọ Nàìjíríà lèrò ọkọ̀, tó ń wo bí èmi àtàwọn mínísítà mi yóò ṣe jáfáfá sí – Tinubu

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Emi ni awakọ, gbogbo awọn ọmọ Naijiria ni wọn joko si ẹyin mi ti wọn si n woye bi emi ati yin ṣe n tukọ yii. si ni ero ọkọ yii”

Ọrọ ti aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu sọ fun awọn minisita tuntun to ṣẹṣẹ bura fun gẹgẹbi ọmọ igbimọ iṣejọba apapọ orilẹede Naijiria.

Aarẹ Tinubu ni gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo n reti igbesẹ akin eyi ti yoo mu ireti ọtun ti iṣejọba oun duro le lori jade.

O ni gbogbo awọn minisita yii lo ni ipa lati ko lọna ati ri pe gbogbo ileri wọnyi bọ sii fun wọn.

Aworan gbọngan ti ibura naa ti waye

Oríṣun àwòrán, screenshot

O ni gbogbo awọn minisita naa gbọd mọ wi pe awọn kii ṣe minisita agbegbe koowa wọn tabi ipinlẹ ti wọn ti wa bikoṣe aṣoju orilẹede Naijiria lapapọ.

Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣeto eto ibura fun awọn minisita tuntun fun igbimọ iṣakoso ijọba apapọ ti wọn ṣẹṣẹ yan lọjọ Aje.

Awọn minisita marundinlaadọta ni aarẹ bura fun ni gbọngan igbalejo nla to wa ni ile aarẹ ni Aso Rock Villa nilu Abuja.

Awọn minisita tuntun

Awn kan lara awọn minisita naa.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Awọn minisita ti wọn bura fun lọjọ Aje niwọnyii:

  • Minisita fun ọrọ abẹle, Bunmi Tunji-Ojo
  • Minisita fun ibanisọrọ, ọgbọn inu ati ọrọ aje igbalode, Bosun Tijani
  • Minisita fun eto iṣuna ati ọrọ aje, Wale Edun
  • Minisita fun ọrọ aje inu omi, , Adegboyega Oyetola
  • Minisita fun ohun amuṣagbara, Adedayo Adelabu
  • Minisita keji fun eto ilera ati igbayegbadun araalu Tunisia Alausa
  • Minisita fun idagbasoke ohun alumọni ilẹ, Dele Alake
  • Minisita fun irinajo afẹ, Lola Ade-John
  • Minisita fun idaleeṣẹsilẹ, katakara ati idokoowo, Doris Anite
  • Minisita fun imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Uche Nnaji
  • Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Nkiruka Onyejeocha
  • Minisita fun ọrọ awọn obinrin, Uju Kennedy
  • Minisita fun iṣẹ ode, David Umahi
  • Minisita fun idagbasoke ẹkun Niger Delta, Abubakar Momoh
  • Minisita fun eto igbogun ti iṣẹ, Betta Edu
  • Minisita fun idagbasoke afẹfẹ gaasi, Ekperikpe Ekpo
  • Minisita fun epo rọbi, Heineken Lokpobiri
  • Minisita fun irinna ofurufu Festus Keyamo
  • Minisita fun ere idaraya, John Enoh
  • Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesom Wike
  • Minisita fun aṣa, iṣe ati ọrọ aje ẹbun ọpọlọ, Hannatu Musawa
  • Minisita eto abo, Mohammed Badaru
  • Minisita keji fun eto abo, Bello Matawalle
  • Minisita keji fun eto ẹkọ, Yusuf T. Sunumu
  • Minisita fun ileegbe ati idagbasoke ilu, Ahmed M. Dangiwa
  • Minisita keji ileegbe ati idagbasoke ilu, Abdullah T. Gwarzo
  • Minisita fun ato ọrọ aje, Atiku Bagudu
  • Minisita keji fun olu ilu Naijiria, Mairiga Mahmud
  • Minisita keji fun ipese omi ati imọtoto ayika, Bello M. Goronyo
  • Minisita feto Ọgbin ati ipese ounjẹ, Abubakar Kyar
  • Minisita feto ẹkọ, Tahir Maman
  • Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Yusuf M. Tuggar
  • Minisita fun eto ilera, Ali Pate
  • Minisita fun ọrọ awọn ọlọpaa, Ibrahim Geidam
  • Minisita keji fun idagbasoke irin tutu, U. Maigari Ahmadu
  • Minisita fun idagbasoke irin tutu, Shuaibu A. Audu
  • Minisita fun eto iroyin, Muhammed Idris
  • Agbẹjọro agba ati minisita fun eto idajọ, Lateef Fagbemi
  • Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Simon B. Lalong
  • Minisita keji fun awọn ọlọpaa, Imaan Sulaiman-Ibrahim
  • Minisita fun akanṣe iṣẹ ati ajọṣepọ awọn ẹka ijọba, Zephaniah Jisalo
  • Minisita fun ọrọ omi ati imọtoto ayika, Joseph Utsev
  • Minisita keji fun eto ọgbin ati ipese ounjẹ, Aliyu Sabi Abdullahi