Ọ̀pọ̀ bú mi pé mo sanra jù lái mọ̀ pé oyún bọ́ lára mi – toyin Abraham tú àṣírí bó ṣe ṣẹlẹ̀

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Mo loyun ri amọ mo padanu rẹ laipẹ yii”


Toyin mẹnu ba ọrọ bi oyun to ni laipẹ yii ṣe bajẹ lara rẹ to si sọ bi o ṣe bori akoko naa.

“Ṣe ẹ mọ pe lọpọ igba awọn eeyan o tilẹ mọ nnkan ti a n la kọja, igba ti mo gbọ awọn ọrọ yẹn, mo sọkun gidi gan.”

Toyin Abraham ni awọn mii bu oun pe “o tisanra ju, wo bi ọkọ rẹ ṣe n dan ti iwọ kan ṣaa sanra, amọ ko ye wọn.”

Toyin ni oṣere to ba n ka ọrọ awọn eeyan si yoo kan pa ara rẹ torinaa oun kan maa yọ ẹni ti ọrọ rẹ ba fẹ ba oun ninu jẹ kuro loju opo oun ni.

“A ti ni ọmọbinrin a si ni ọmọbinrin, bi akoko ba to, oyun yoo duro.”

Toyin Abraham ati Seun Egbegbe

Toyin Abraham ni “ṣe mọ pe awa obinrin maa n ni imọlara nnkan gan, a maa n fẹ ki gbogbo eeyan ba ẹni to ba ṣe ika fun wa ja, ti ko ba si ri bẹẹ, inu wa kii dun.”

O ni nigba naa oun jẹ ọmọde, oun si ro pe gbogbo eeyan lo kẹyin si oun ti aye si n dawo le oun lori afi igba ti oun pade ọga rẹ to gbe e sita nipasẹ awọn fiimu ede Oyinbo, iyẹn lo fi jade kuro lara awọn oṣere Yoruba lẹyin iriri rẹ pẹlu ọkọ afẹsọna rẹ tẹlẹ..

“Iṣẹ gidi ni mo ṣe lati bori akoko naa, ọpọ adura. Mo kan sọ fun ara mi pe Toyin o ni lati tẹsiwaju, kii ṣe bi Ọlọrun ṣe fẹ niyii, mo si tẹsiwaju ninu adura.”

“Afadurajagun ni ọkọ mi Kolawole Ajeyemi”

Toyin ati Kolawole

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Toyin Abraham ni ọkọ ohun ti oun fẹ yii, Kolawole Ajeyemi ni ohun to dara ju to ṣẹlẹ si oun laye oun.

“Ẹgbọn lo jẹ fun mi lẹnu iṣ bo tilẹ jẹ pe oniwa tutu ni amọ lori itage, “fii lẹ fun un”. Ẹwẹ, loju aye gangan, agbadura jagun ni o!”.

Toyin Abraham ṣalaye bo ṣe maa n tẹlee lọ fun ere titi ti awọn eeyan ṣe mọ wọn pọ ti awọn mejeji si lọ fi ara wọn han obi wọn.

“Awọn ẹbi mi kọkọ bẹru tori pe inu agbo oṣere naa ni mo tun ti mu ẹlomiran wa amọ idile Kristẹni ni mo ti wa torinaa, awọn bi mi gbadura nipa rẹ wọn si ni o dara.”

O ni ṣugbọn wọn sọ fun oun pe oun gbudọ tẹriba gidi gan.

Toyin ni awọn ẹbi oun gbadura nigba afẹsọna akọkọ oun naa wọn si s fun oun pe kii ṣe toun amọ oun ṣe ori kunkun.

“Emi ati ọkọ mi o da owó iṣẹ́ pọ̀”

Toyin Abraham ni lootọ oun ati ọkọ oun maa n ṣe ere pọ, awọn si maa n ba ara awọn polowo ere loju opo Youtube awọn mejeeji amọ to ba ti de ibi owo, ọtọọtọ ni katakara awọn.

Amọ o ṣalaye pe oun maa n ya owo lọwọ ọkọ oun ti ọkọ rẹ naa si maa pee lati kopa ninu ere rẹ ti oun yoo bere owo iṣẹ lọwọ́ rẹ amọ ti awọn yoo fi ẹrin pari rẹ.

“Ọkọ mi ti sọ fun mi lati ibẹrẹ pe bi mo ba wa ninu ile, iyawo ni mi amọ lori itage, ki n gba pe oṣere ni mo jẹ mo dẹ ti gba bẹẹ.”

Toyin ni gẹgẹ bi oun ṣe ti di atọkun ere bayii, oun maa n tete ri iṣẹ oun ṣe toripe o ni ibaṣepọ to dara pẹlu awọn eeyan.

Ẹwẹ, o ni oju ti awọn eeyan ko mọ loun fẹ maa lo gẹgẹ bi olukopa to ṣe pataki julọ ninu awọn fiimu ohun.

“Mo le fi gbogbo ẹnu sọ fun yin pe mo wa lara awọn oṣere to lowo ju, bẹẹ ni!”

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Mo jẹ eeyan to gbaju mọ iṣẹ gan ni mo ṣe ń pa Miliọnu Miliọnu ninu iṣẹ Tiata yii”

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Toyin Abraham-Ajeyemi ti sọ idi ọrọ rẹ ninu iṣẹ Tiata to yan laayo.

Nigba to n sọrọ lori eto kan to wa fawọn ọdọ lori amohunmaworan Channels ni toyin Abraham ti ṣalaye nipa ara rẹ pe lati ọmọ ọdun marun ni oun ti bẹrẹ si ni pa owo nidi ere fiimu ṣiṣe.

Amọ nigba to ṣe fiimu nla kan to tan ka, o ni oun ko le sun pẹlu aduru owo ti oun ri ni asuwọn owo oun.

“Nigba ti awọn ti mo ba ṣiṣẹ pe mi lori foonu pe wọn ti fi owo iṣẹ mi ranṣẹ sinu asuwọn owo mi, ti mo ri miliọnu Mẹtadinlaadọta, mi o le sun mọju, ẹru n ba mi bii pe awọn to ni fiimu gangan yoo wa pa mi lati gba owo naa koda mo pe iya mi ninu Oluwa lori rẹ.”

Nibayii mo le sọ fun yin pe mo wa lara awọn to lowo ju lagbo oṣere.”

“Idi ti mi o fi si lagbo oṣere Yoruba mọ”

̀Toyin Abraham ni kii ṣe pe oun kuro laarin awọn oṣere Yoruba, tori orisun oun ni, obi oun si ni.
́“Ibi ti mo ti bẹrẹ niyẹn, awọn lo dabii obi mi.

Amọ ṣẹẹ mọ Yoruba maa n ni ti ọmọde ba to lọkọ, wọn maa n fun un ni ọkọ ni torinaa, kii ṣe tori owo ni mo ẹ kuro laarin wọn.”

Ibi yii gaan ni Toyin Abraham ti lahun pe ọrọ nipa ọkọ afẹsọna ti oun n fẹ tẹlẹ lo fa sababi bi oun ṣe kuro lagbo oṣere Yoruba.

“Nigba ti mo wa lagbo oṣere Yoruba, owo ṣinpini ni wọn maa n fun wa amọ nisinyii…”

Toyin Abraham ni kii ṣe tori owo ni oun ṣe bẹrẹ fiimu ṣiṣe, o ni oun kan ṣaa nifẹ lati kopa ninu ere ni.

“Eeyan kan ṣaa maa n gbadura pẹlu ọrọ Yoruba to maa n sọ pe “o maa daa, o maa daa, iwọ naa a dẹ maa tii lọ tori ifẹ ti mo ni sii, bo tilẹ jẹ pe owo ti mo le fi jẹun wa nigba naa amọ ko to.