Zinder, ìlú tí “àwọn èèyàn tí a yà sọ́tọ̀ fún òṣì àti ìṣẹ́ ń gbé”

Ilu Zinder jẹ ilu kan ni gusu orilẹede Niger. Agbegbe to kun fun ọpọlọpọ ifarahan iṣẹ ati oṣi ni.

Koda awọn olugbe agbegbe naa kan gbagbọ pe “awọn eeyan ti a sọtọ fun oṣi ati iṣẹ n gbe” ni Zinder.

Gẹgẹ bi ọrọ to n waye lọpọ awọn awujọ ni awọn orilẹede to ku diẹ kaato fun, iṣẹ ati airiṣẹ ti sọ ọpọ awọn ọdọ nibẹ di janduku ati ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Awọn iwa ipa bii ipaniyan, ifipabanilopọ atawọn iwa kotọ miran ko ṣai wọpọ ni awujọ naa.
O le ni ọọdunrun ẹgbẹ okunkun to wa nibẹ, gẹgẹ bi abajade iwadii kan ti ajọ agbaye UNICEF gbe kalẹ lọdun 2012.
Siniboy to jẹ aṣiwaju ọkan ninu awọn ẹgbẹ okunkun naa ṣalaye fun BBC pe, “bi ija ba ṣẹlẹ awa maa tori bọọ. Bi ẹgbẹ kankan ba yaju si wa, a maa lu wọn.”