Lẹ́ẹ̀kan síi!!! Àwọn agbébọn kọlù ọfíìsì INEC ní Imo, èèyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mi wọn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afurasi agbebọn ọhun ṣekupa ọlọpaa kan ati eyan mẹta miiran lẹyin ti wọn ju ado oloro si ọfiisi ajọ eto idibo INEC ni Owerri nipinlẹ Imo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Mike Abattam ni awọn agbebọn to to mẹwaa ni wọn de si ọfisi ajọ ọhun ni dede ago mẹta owurọ pẹlu ado oloro.

O fikun un pe awọn agbebọn naa gbe ogun ija kọlu ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si ṣekupa ọlọpaa kan.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa mu mẹta balẹ ninu awọn agbebọn ọhun.

Awọn apa ibi kan ni ofiisi ajọ INEC ni ina mu, to si jona.

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

“Wọn ṣe ikọlu si ọfisi ajọ INEC ni Owerri ni bi ago mẹta ooru. Wọn ju ado oloro sori orule ile naa sugbọn ko ṣe awọn ọlọpaa lese, wọn wa pẹlu ọkọ mẹrin pẹlu awọn ibo nla.

“Wọn kọju ija si ileeṣẹ ọlọpaa, ti wọn si sa lọ nigba ti wọn rii pe ipa wọn ko le ka wa, ti wọn si fi ọkan ninu ọkọ wọn silẹ. A tẹle wọn ti a si mu mẹta balẹ ninu wọn lopopona Onitsha.

Bakan naa ni lo ni awọn yooku gbe oju apa ibọn sa lọ. Sugbọn, ọkan lara awọn ọlọpaa ba ikọlu naa lọ, ti ẹlomiiran si farapa .

“A gba ibọn ati ọkọ lọwọ wọn janduku yii.”

Igbakeji ree ti wọn yoo ṣe ikọlu si ọfisi INEC laarin ọsẹ meji

Ọjọ kẹrin, Oṣu Kejila ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, sọ pe awọn agbebọn yabo ọfiisi rẹ to wa ni ijọba ibilẹ Orlu nipinlẹ Imo.

Ni nnkan bii aago mẹrin idaji ọjọ Aiku ni ikọlu naa waye.

Eyi waye lẹyin awọn agbebọn kan kọlu ọfiisi rẹ to wa ni ijọba ibilẹ Orlu, lọjọ Kinni, Oṣu Kejila, nipinlẹ Imo bakan naa.

INEC sọ pe ọfiisi rẹ keje niyii ti awọn agbebọn ṣe ikọlu si ni ipinlẹ marun-un, laarin oṣu mẹrin pere.