Kàyéfì! Orílẹ̀èdè Nàìjíríà ló lùgbàdì àìsàn Ìbà jù lágbàyé – Àjò WHO

aworan kokoro ẹfọn

Oríṣun àwòrán, MichaelSemple/facebook

Ajọ eto ilera lagbaye WHO ti kede orilẹede Naijria gẹgẹ bii orilẹede ti ọpọ awọn eeyan ti lugbadi aisan iba ju lagbaye pẹlu orilẹede Democratic of Congo.

WHO, ninu atẹjade rẹ to fi lede nipa aisan iba fun ọdun 2021, ni Naijiria ati Congo ni aisan iba naa ti ba awọn eeyan finra ju lagbaye.

Atẹjade naa ni Naijiria ni ida Mọkanlelọgbọn eeyan lagbaye ti wọn ku nipa sẹ aisan iba, DRC ni ida mẹtala (13) lagbaye, ti awọn orilẹ-ede meji miiran ti o tẹle e lẹyin Niger Republic ni ida mẹrin (4) ati Tanzania, ida Mẹrin ninu ida Ọgọrun.

Nigba to boju wo ipa  ti aisan COVID-19 ko lagbaye lọdun 2021, ajo naa sọ pe iye awọn ti aisan iba ti wọn ni pọ ju bo ṣe yẹ lọ.

Ninu akọsilẹ miiran, awọn to lugbadi aisan iba jẹ miliọnu mẹtadinlaadọtalenigba ti awọn to baa lọ si le ni ẹgbẹrun Mẹsan lọdun 2021.

Eyi ṣafihan ilọsoke ninu awọn to lugbadi aisan iba ti o jẹ miliọnu meji ti idinku  si ba awọn ti wọn ba aisan naa lọ nigbati aisan COVID-19 bẹrẹ  ni ọdun 2021 sì Millionu Mẹfa.

aworan awọn ibora idaabobo araẹni lọwọ ẹfọn

Oríṣun àwòrán, who/facebook

Ninu abọ iwadii ti ajọ ọhun, ida Mẹrindinlọgọrun lo pade iku nipasẹ aisan iba ninu orilẹede mọkandinlọgbọn kari aye. 

Awọn orilẹede mẹrin ni o ko  idaji gbogbo awọn tiku pa nipasẹ aisan iba ni agbaye  lọdun 2021: Nigeria (31%), Democratic Republic of Congo (13%), Niger (4%), ati United Republic of Tanzania (4%).  ”

Ajo WHO lọdun 2021, pin awọn apo to ni ogun Ẹfon lara laarin ọdun yii eleyi ti o to miliọnu Mejidinlaadoje niye.