Ènìyàn Mẹ́ta kú, Mẹrin Farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe rọ́lu àwọn ènìyàn ni Mokola ní Ibadan

Ijamba

Oríṣun àwòrán, Others

Eniyan mẹta ni iroyin ti sọ pe o ku ti mẹrin si farapa ni ọsan ọjọ abamẹta bi àgbo ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọ inu ihade Mokola ni Ibadan.

Awọn ọkọ ati awọn alupupu tun bajẹ lakoko iṣẹlẹ naa

Ẹlẹri o ṣe oju mi koro kan sọ fún àwọn oniroyin pe ọkọ epo ti kan tí ìjánu rẹ ja lo lọ rọ́lu àwọn kan nínú ilepo kan.

Alaga fun ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ ni ipinlẹ Ọyọ (OYRTMA), Mogaji Akin Fagbemi sọ pe ijamba naa waye ni aago mọkanla aabọ aarọ ti ọkọ gaasi kan (richbam) pẹlu nọmba iforukọsilẹ: MAP810YY, ọkọ ayọkẹlẹ Micra meji ati alupupu mẹrin kọlu ara won.

Gege bi ọrọ Fagbemi, o ni idi ijamba náà níṣẹ́ pẹlu bireeki ọkọ to ja Awọn ọrọ :

“Lẹsẹkẹsẹ ti ijamba naa ṣẹlẹ, awọn oṣiṣẹ OYRTMA ti gbe awọn mẹtẹẹta ti wọn farapa, ti wọn sare gbé wọn lọ si UCH, idi ti wọn fi gbe eniyan meji kuro ninu pakute ọkọ nla ti wọn si ti gbe oku naa si ile iwosan Adeoyo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn iṣẹ ìrànwọ́ naa ni o waye nipasẹ OYRTMA pẹlu ifowosowopo àwọn ọlọpa Nàìjíríà, ajọ aabo ara ẹni laabo Ilu ati Operation Burst.

Wọn ti gbe awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti ọrọ náà kan kuro ni opopona ti wọn si gbe lọ si agọ ọlọpa Mokola fun iwadii síwájú si.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ