Áwọn ológun Russia balẹ̀ sí Niger láti kọ́ wọn lógun jíjà

Awon ologun lori oko akotami

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn akọṣẹmọṣẹ ologun lati orilẹ-ede Russia ti balẹ bayii sorilẹ-ede Niger, ki wọn le kọ wọn bi wọn yoo ṣe koju ogun to n kora jọ lapa kan aṣalẹ Iwo-Oorun Afrika.

Ọjọru,ọjọ kẹwaa oṣu kẹrin ọdun 2024 yii ni awọn ologun Russia balẹ si olu ilu Niger ti i ṣe Niamey.

Bi wọn ṣe de ni wọn bẹrẹ si i ja awọn nnkan eelo ogun silẹ lati inu ọkọ ofurufu akẹru to gbe wọn de si Niger.

” A wa sibi lati kọ awọn ọmọ ogun Niger logun jija ni, ka si ri i pe irẹpọ ologun wa laarin Russia ati Niger’’

Bẹẹ ni ọkan ninu awọn ọmọ ogun Russia naa sọ fun ẹka iroyin TV RTN.

Ikọ ologun ti yoo ja lofurufu yoo wa nibẹ pelu.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tó fi di pé ológun Russia balẹ sí Niger?

Latigba ti awọn ologun ti gbajọba ni Niger lọdun to kọja ni Niger ti bẹrẹ ajọṣepọ pẹlu Russia.

Eyi ri bẹẹ nitori Niger n wa iranlọwọ lori ọrọ aabo, wọn si gba pe agbara n bẹ ni Moscow ti i ṣe olu ilu Russia.

Niger kọyin si France ati Mali, pẹlu Burkina Faso ti wọn jọ mule tira wọn, o si kọju si Russia pẹlu igbagbọ pe iranwọn yoo tibẹ wa.

Wọn ni Russia yoo bawọn ṣẹgun awọn ikọ alakatakiti ẹsin to n ṣuyọ.

Àwọn irinṣẹ̀ ogun tí kò sí ní Niger tẹ́lẹ̀ balẹ̀ gíd̀̀ígbá

Agbẹnusọ awọn ologun to gbajọba ni Niger, Ọgagun Amadou Abdourahamane, ṣalaye lori tẹlifiṣan ilu naa pe awọn ti ba Aarẹ Vladmir Putin ti Russia sọrọ lori ajọṣepọ yii.

“ Awọn ologun Russia yoo kọ awọn ti Niger.

Bakan naa ni wọn tun ko awọn nnkan ija tuntun ti ko si ni Niger tẹlẹ wa.

Wọn yoo gbe wọn kalẹ sawọn aaye to yẹ ki wọn wa, wọn yoo si kọ awọn ọmọ ogun Niger ni lilo wọn.

Lara awọn nnkan ohun ni eyi ti wọn yoo lo loju ofurufu.’’

Ǹjẹ́ ààbò ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ológun gbàjọba Niger?

Eto aabo to mẹhẹ pupọ ni awọn ologun tori ẹ gbajọba lọwọ Mohamed Bazoum to n ṣejọba ilu naa tẹlẹ.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje ọdun 2023 ni ologun yẹ aga mọ Bazoum nidii, ti wọn si gba agbara lọwọ rẹ.

Ṣugbọn iroyin to n jade fi han pe awọn agbesunmọmi ṣi n kọlu apa kan orilẹ-ede Niger, paapaa lapa ibi ti wọn n pe ni Tillabery.

O fẹrẹ jẹ pe oṣooṣu ni wọn n kọlu awọn eeyan ibẹ bi iroyin ṣe sọ.

Bi ikọ Boko Haram ṣe n daamu awọn eeyan lapa kan Naijiria, bẹẹ ni Nijee naa n koju iṣoro awọn alakatakiti ẹsin to n ṣuyọ lagbegbe wọn.

Ajọṣepọ ti Niger n ba Russia ṣe yii bẹrẹ lẹyin ọjọ diẹ ti o kere tan, ṣọja mẹfa ku ninu ibugbamu kan to waye ni Tillabery, nitosi ẹnu ibode Mali.

Bakan naa lo n waye lẹyin ti awọn ologun Niger fawe adehun ajọṣepọ aarin oun ati orilẹ-ede Amẹrika ya.

Ṣugbọn awọn ologun Amẹrika ṣi n ba awọn ti Niger sọrọ lati jẹ kawọn eeyan wọn wọle si Niger.

Bo tilẹ jẹ pe ifa Russia lo n fọre leti awọn ologun Nijee lọwọlọwọ.