“Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́ 276 gbé ní Chibok, mo ṣì ń retí ọmọ mi”

Ọdun mẹwaa sẹyin ni awọn agbesumọmi ji akẹkọbinrin ti iye wọn jẹ 276 gbe ni niluu Chibok, ni Ariwa Naijiria.

Inu oṣu Kerin ọdun 2014 ni iṣẹlẹ naa waye, iṣẹlẹ ọhun si ti da ọgbẹ ayeraye si ara ilu naa ati ọkan awọn eeyan rẹ.

Gbogbo agbaye lo gbọ nipa iṣẹlẹ naa lọdun naa lọhun, ti ọpọ eeyan kaakiri agbaye si ke si awọn ijọba orilẹeede agbaye lati doola awọn akẹkọọbinrin naa pẹlu ami #bringbackourgirls lori ayelujara.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti gbagbe nipa iṣẹlẹ yii, ọpọ awọn olugbe ilu naa lo n sọ pe bi ana ni ọrọ ọhun ṣi ri loju awọn.

Dorcas Yakubu wa lara awọn ọmọ ti wọn ji gbe, ọmọ naa ko si tii pada wale titi di oni yii lẹyin to farahan ninu fidio kan lọdun 2016.

Chibok girls

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma

Ninu ifọrọweọ pẹlu BBC, iya Dorcas sọ pe ojojumọ ni oun maa n ronu nipa ọmọ naa, ti oun si maa n gbadura fun nibiki to ba wa.

Iya akẹkọọ mii ti wọn ji gbe, iyẹn Rebecca Samuel, sọ pe oun gbagbọ pe ọmọ oun ṣi maa pada wale.

Iya Rebecca sọ pe ọmọ naa yoo pada wale lọjọ kan bo tilẹ to ogun .

Ẹwẹ, ọga agba ile ẹkọ awọn akẹkọọbinrin ọhun, Muhammad Chiroma sọ pe ijọba ti ṣatunṣe rẹ, awọn ologun si n sọ agbege rẹ loorekoore.

Chiroma ni awọn akẹkọọ tuntun ni awọn n gba wọle ni gbogbo igba.

Sẹnetọ to n ṣoju Chibok, Ali Ndume ni tirẹ sọ pe ijọba ko gbabe ilu naa, ijọba si n ṣiṣẹ lọwọ lati doola awọn akẹkọo Chibok atawọn mii to wa lakata awọn ajinigbe.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí