Ìgbìmọ̀ afọbajẹ ilẹ̀ Ibadan kéde Olubadan tuntun

Olubadan of Ibadan

Oríṣun àwòrán, bbc

Igbimọ afọbajẹ Olubadn ilẹ Ibadan ti kede Ọba Owolabi Olakulehin gẹgẹ bii Olubadan ikẹtalelogoji nilẹ Ibadan.

Ni ibi ipade igbimọ Olubadan to waye lọjọ Ẹti ninu aafin Olubadan ilẹ Ibadan to n bẹ ni agbegbe Ọj’aba, niluu Ibadan ni wọn ti kede Olubadan tuntun naa.

Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Oloye Rashidi Ladọja to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa ṣe alaye wi pe awọn ti yan Olubadan tuntun gẹgẹ bii igbimọ afọbajẹ.

O ni “o wa ku si ọwọ Gomina lati fi ọwọ sii pe oun gba”.

Ladọja ni ko si idi rẹ ti Gomina ko fi ni gba nitori igbesẹ ti o ni atilẹyin ofin ni awọn gbe.

O ni ti Gomina ba ti fi ọwọ sii tan, ohun ti o ku naa ni ki wọn da ọjọ ayẹyẹ ifinijoye.

Olubadan

Oríṣun àwòrán, bbc

O gbadura wi pe igba Olubadan tuntun yoo tu t’ẹru-t’ọmọ lara.

Saaju asiko yii ni ọpọlọpọ awuyewuye ti rọ mọ iyansipo Olubadan ilẹ Ibadan nitori ilera Ọba tuntun naa.

Awayi o, ni bayii ti awọn igbimọ Olubadan ti kede rẹ gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun, ohun to ku naa ni Gomina buwọ luu, ki wọn si da ọjọ ayẹyẹ ifinijoye.

“Ọ̀la ni a máa ṣe ìpàdé láti yan Olubadan tuntun, kìí ṣe gómìnà ló máa yan ọba fún wa”

Ladoja

Oríṣun àwòrán, BCOS

Pẹlu Awuyewuye to n waye lori ọrọ ta lokan lati gun ori itẹ olubadan ti ilẹ Ibadan.

Oloye Adewolu Ladoja to jẹ ọtun Olubadan ti feṣi si ọrọ ti oloye agba Ọba Ajibola sọ pe ara ọba Olakuleyin ti oyẹ olubadan tọ si ko le daadaa.

O sọ pe awọn onimọ nipa eto ilera nikan ni wọn ni anfani lati sọ nipa ilera ẹnikẹni.

Ladoja ni amofin ni ọba Ajibola, kii ṣe onimọ nipa eto ilera niotori naa ko si ohunkohun to se ara ọba Olakuleyin, koko lara baba le.

O tun fi kun pe ọba Olakuleyin kii ṣe ọmọ ọgbọn ọdun, ẹni to ju ọmọ ọgọrin ọdun lọ ni ko si ṣee ṣe ki ara rẹ da bii ọmọ ogun ọdun.

O ni “arugbo naa ti ṣoge ri ati pe ọmọ ologun ni baba nigba to wa ni ewe, ẹjẹ ka gbagbe wipe ara olubadan ko ya.”

Ọtun Olubada fi kun pe “lati ọdun 1983 ni ọba Olakuleyin ti n gun akasọ yi bọ lati joye olubadan ṣugbọn Ọlọrun nikan lo n fi ọba jẹ.

“Nitori ari ọpọlọpọ awọn to wa ni ipo ọba Olakuleyin wa yii ṣugbọn ti wọn ko de ipo Olubadan, ti Ọlọrun ba ka wọn yẹ lati de bẹ ko si ẹnikẹni ti yoo di lọna erongba rẹ.

“Ohun ti ofin ṣọ ni pe a gbọdọ yan ọba tuntun larin ọgbọn ọjọ nitori idi rẹ ni ipade yoo fi waye ni ọla.

“Lẹyin naa a maa lọ gbe orukọ ẹni ti a ba yan fun gomina lati buwọlu, kii ṣe gomina lo maa yan ọba fun wa ṣugbọn gomina ni aṣẹ lati ni ki a lọ mu ẹlomii wa ti ẹni ti a yan ko ba yẹ loyẹ.”

Ìdí rèé tí Olubadan tuntun kò ti fíì gorí oyè di àkókó yìí – Otun Balogun ṣàlàyé

Aworan Ọba Owolabi Olakulehin

Ọtun Balogun Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Abimbola Tajudeen Ajibola, ti rọ awọn awọn afọbajẹ lati fun ẹni ti oye Olubadan kan, Oba Owolabi Olakulehin laye diẹ si ki o to gori oye.

Ọba Ajibola sọrọ yii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.

‘’Ki Olubadan to le jẹ, awọn eto kan wa ti ẹni ti oye kan ni lati ṣe ki o to jọba.

Ọrọ jijẹ Olubadan kii kan ṣe wi pe ti ẹni to wa lori oye ba ti ku, ki ẹni to kan ṣi bọ sori oye ni kiakia.

Awọn nnkankan wa ti ẹni ti oye Olubadan kan gbọdọ ṣe daadaa ki o si yege, bi bẹẹ kọ, ẹni naa ko ni gori oye.

Ara awọn amuyẹ ti ẹni ti oye Olubadan kan gbọdọ ni ni pe ko gbọdọ ti wa lẹwọn ju oṣu mẹta lọ ri.

Ilera ara rẹ gbọdọ gbọdọ da muṣe muṣe, ko gbọdọ ya odi tabi ki o ma gbọran daadaa, o gbọdọ le rin daadaa fun ra rẹ.

Ẹni ti yoo jẹ Olubadan gbọdọ le bawọn eeyan sọrọ daadaa, ko si gbọdọ ṣe ohun ti yoo pa ilu Ibadan lara.

Koda, ti awọn afọbajẹ ba fi orukọ ẹni ti oye kan ransẹ si gomina gan an, ko tumọ si pe gomina yoo kan buwọlu orukọ ẹni naa lai ni gbogbo amuyẹ to yẹ ki o ni.

Gomina le buwọlu ẹlomiran ti ẹni ti oye kan ko ba kun oju oṣuwọn to.

Koko ohun ti mo n sọ ni pe a ko ti i yan Olubadan tuntun, asiko ko tii to lati yan Olubadan tuntun.

Bakan naa, asiko yii kọ ni asiko ti a gbọdọ maa pẹtu sija.

Ko si ija tabi ikunsinu kankan ti ẹnikẹni fẹ sọ pe oun fẹ pari lasiko yii.

Bo ya ọrọ naa ko ye ọpọ awọn eeyan wa daadaa ni, awọn kan sọ pe Olubadan tuntun ti gbe owo kalẹ.

Ki i ṣe ọrọ owo lowa nilẹ yii, ṣe o le ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bi ọba?

Ti o ba ti le ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bi Olubdan, ohun ti a n fẹ niyẹn,’’ Otun Balogun Olubadan lo sọ bẹẹ.

Ṣáájú ni Ọtun Balogun Ibadan ti kọ́kọ́ sọ pé ara Olubadan tuntun kò dá pé tó láti di ipò náà mú tí àwon míì sì n sọ pé ṣé kìí ṣe pé Ibadan ti n bá ọ̀tẹ̀ bọ̀ báyìí lórí jíjẹ́ Olubadan tuntun.