Yàtọ̀ sí Akeredolu, kà nipa àwọn gómìnà àti èèkàn olóṣèlú míràn tí ikú já ìràwọ̀ wọn lórí oyè ní Nàìjíría

Aworan awọn Gomina ati eekan to ku lori oye ni Naijiria

Iku Gomina Rotimi Akeredolu le jẹ akọkọ ti Gomina ipinlẹ Ondo to ku lori oye ṣugbọn ninu akọsilẹ lorileede Naijiria ohun ni Gomina ẹlẹkẹẹrin iru rẹ ti yoo papoda lori aleefa.

A rii ka ninu itan pe Sheu Kangiwa ipinlẹ Sokoto dagbere faye lọdun 1981 lori alefa.

Oun ni Gomina akọkọ ti wọn dibo yan ni abala ijọba awarawa ẹlẹẹkeji ni Naijiria.

Oṣu Kọkanla 1981 lo ku nigba to jabọ lori ẹsin nibi to ti n ṣe ere idaraya Polo.

Bẹẹ naa ni Mammaan Ali ti ipinlẹ Yobe to ku lori oye lọdun 2009.

Leukaemia lo ṣokunfa iku rẹ taa si gbọ pe Florida lorileede America lo dakẹ si nibi to ti n gba itọju.

Gomina Kẹrin taa darukọ ni Patrick Yakowa ti ipinlẹ Kaduna.

Ọdun 2012 lo kagbako iku ninu ijamba ọkọ abasibi owu iyẹn helikọpta.

Yakowa ni Gomina akọkọ to jẹ Kristẹni ti yoo de ori aga ni ipinlẹ Kaduna.

O ṣe ṣaaju rọpo igbakeji Gomina labẹ ijọba Gomina Makarfi Stephen Shekari to ku lori oye.

Wọn ko dibo yan Yakowa sipo Gomina bi kii ṣe pe o bọ sipo naa lẹyin ti aarẹ Goodluck Jonathan yan Gomina Namadi Sambo gẹgẹ bi igbakeji aarẹ lẹyin ti oun naa bọ si ipo aarẹ lẹyin iku Aarẹ Umaru Musa Yar Adua.

Yatọ si awọn Gomina wọnyii, diẹ ree ninu awọn eekan ilu to dipo mu to si jad elaye lori ipo naa.

Aarẹ tẹlẹ Umaru Musa Yar’Adua

Aworan aarẹ Yar'Adua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Naijiria tẹlẹ Umaru Musa Yar’Adua ku sori oye loṣu Karun un ọdun 2010 lẹni ọdun mejidinlọgọta.

Lori ẹrọ amohunmaworan ni wọn ti da eto kan to n lọ lọwọ duro lati kede iku rẹ.

Adele Aarẹ to wa lori ipo nigba naa Goodluck Jonathan lo pada bọ si ipo gẹgẹ bi aarẹ.

Bii ti Akeredolu to ṣe aarẹ lori ipo, o to ọjọ meloo kan ti Yar’ Adua naa fi ṣaarẹ ko to di pe ọlọjọ de.

Lasiko to fi n gba itọju nile iwosan kan lorileede Saudi ọpọlọpọ awuyewuye lo

ṣẹlẹ lori boya ki Goodluck Jonathan igbakeji rẹ maa ṣe adele aarẹ tabi ko bọ si ipo aarẹ.

Iku lo pada yanju ọrọ naa tori wọn bura wọle fun sipo to si di aarẹ lẹyin iku Yar’Adua.

Aworan Sẹnẹtọ Isiaka Adeleke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Isiaka Adeleke

Isiaka Adeleke(1955–2017)

Nigba ti yoo fi jade laye, Isiaka Adeleke ti ọpọ mọ si Serubawọn ni Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Osun nile aṣofin agba Naijiria.

Oṣu Kẹrin ọdun 2017 lo faye silẹ nileewosan kan nilu Osogbo lẹyin ipade oloṣelu kan to kopa ninu rẹ fun ọpọ wakati.

Titi di asiko to faye silẹ, Adeleke ni alaga igbimọ ile to n mojuto ọrọ idokowoo.

Saa keji lo n lo lọwọ nile aṣofin agba.

Lọdun 1992 ni wọn dibo yan gẹgẹ bi Gomina alagbada akọkọ lẹyin ti wọn da ipinlẹ Osun silẹ.

Pepperito, Abba Kyari ati Rose Oko

Sẹnẹtọ Bayo Osinowo (1955–2020)

Pepperito ni ọpọ mọ gbajugbaja oloṣelu ipinlẹ Eko yi si.

Lasiko ti aarun Coronavirus n ja rain ni Naijiria ni Bayo Osinowo jadelaye.

Aarun yi lo mu lọ gẹgẹ bo ṣe mu ọpọ eekan lọ ni Naijiria.

Osinowo ni Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo ila oorun Eko nile aṣofin agba Naijiria.

Wọn tun fi jẹ alaga igbimọ ileeṣẹ nile aṣofin agba.

O dagbere fun duniya lẹni ọdun mẹrinlelọgọta.

Saaju asiko yi o jẹ aṣofin nile aṣofin ipinlẹ Eko fun dun mọkanla.

Rose Oko (1957–2020)

Ṣaaju ko to jade laye,Rose Oko ni Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Cross River nile aṣofin agba Naijiria.

Bakan naa lo jẹ alaga igbimọ ile lori ọrọ karkata ati idokoowo.

O dakẹ si ile iwosan ni ilẹ Gẹẹsi lẹyin ọsẹ meloo kan to ti n koju aisan ẹjẹ ruru.

Abba Kyari (1952–2020)

Abba Kyari ni Olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Naijiria titi di asiko to fi jade laye.

O jẹ igi pataki lẹyin ọgba aarẹ Muhammadu Buhari lasiko to n ṣe ijọba.

Coronavirus lo mu ẹmi Abba Kyari lọ nileewosan kan nilu Eko lọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹrin.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin nii ṣe.

Lọjọ keji lawọn eeyan peju sibi isinku rẹ nilu Abuja ti awọn araalu si bẹnu atẹ lu bi ero ṣe pọ ni ibi isnku rẹ.

Wọn ni eyitapa si ofin ijinasiraẹni ti ijọba gbe kalẹ nipa isinku awọn eeyan lasiko Coronavirus.

Ninu akọsilẹ, ko fẹẹ si olori awọn oṣiṣẹ aarẹ to lagbara to si lo ọla bi ti Abba Kyari.

Lasiko rẹ, ko si ẹnikankan to le ri aarẹ bi Kyari ko ba fi ọwọ si.

Eyi mu ki ọpọ maa foju ẹni ibi wo wi pe oun ati awọn kan lo n dari aarẹ ti ko fi le ṣe daada si araalu.