Wo àwọn èèyàn kan tó ń ja òkú lólè

Aworan ibi isinku

Oríṣun àwòrán, CHARLES OKO

Awọn olugbe ilu Takoradi lapa guusu orilẹede Ghana ti n kọminu lori bawọn ole ṣe yabo ibi isinku to wa ni ilu naa.

Ibi isinku to di titi pa lọdun 2018 tori o ti kun ni wọn ti hu ọpọ iboji to wa nibẹ bayii.

Awọn ole ọhun ji okuta mabu, taisi atawọn nkan meremere miran tawọn eeyan fi ṣe ọṣọ si iboji awọn ẹbi wọn ti wọn sin sibẹ lọ.

Awọn oṣiṣẹ ibi isinku naa sọ pe ni nkan bi oṣu kan sẹyin lawọn ṣe akiyesi yii eleyii to jẹ kawọn pariwo sita.

Aworan ibi isinku Takoradi

Oríṣun àwòrán, CHARLES OKO

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ naa sọ pe ọpọ posi ti wọn fi sin awọn oku lo ti wa nita bayii.

Oṣiṣẹ mii tun sọ pe igba akọkọ ree ti oun yoo ri ibi tawọn eeyan ti n jale ni itẹ oku.

Ọpọ eeyan lo sare lọ si ibi isinku naa lẹyin ti wọn gbọ iroyin naa ninu ilu lati lọ wo o bo ya iboji awọn ẹbi wọn ko si lara awọn iboji ti wọn ti ji nkan lọ.

Aworan ibi isinku Takoradi

Oríṣun àwòrán, CHARLES OKO

‘’Mo sare wa si ibi isinku yii ṣugbọn inu mi dun tori pe ko si ohun to ṣe iboji baba mi,’’ Maame ọkan lara awọn eeyan to lọ wo iboji lo sọ bẹẹ.

Amọ, Maame fẹ ki ijọba ri pe awọn to ṣiṣẹ laabi yii foju wina ofin ni kiakia.

Awọn mii binu si awọn alaṣẹ Sekondi-Takoradi lori iṣẹlẹ naa.

Nana binu sawọn alaṣẹ ọhun tori awọn lo gbowo lọwọ awọn eeyan ki wọn to gbawọn laaye lati sin ẹbi wọn si ibi isinku naa.

Aworan ibi isinku Takoradi

Oríṣun àwòrán, CHARLES OKO

‘’Ti o ba jẹ pe bii iboji kan tabi meji ni nkan yii ṣẹlẹ si ni, ko ba ti dun wa pupọ.

Amọ, eleyii ti pọju, awọn alaṣẹ ni lati dahun awọn ibeere kan lori iṣẹlẹ yii,’’ Nana binu tan.

Ọwọ tẹ ẹnikan lọdun 2018 lẹyin to ji awọn meremere ninu awọn iboju kan loru ni ibi isinku naa.

Wọn afurasi ọdaran ọhun lọ sile ẹjọ, ileẹjọ kilọ fun un wọn si fi i silẹ.

Amọ, idajọ ile ẹjọ yii ko dun mọ awọn alaṣẹ Sekondi-takoradi.

Kini awọn alaṣẹ Sekondi-Takoradi sọ lori iṣẹlẹ naa?

Aworan ibi isinku Takoradi

Oríṣun àwòrán, CHARLES OKO

Abdul Karim Wudu to jẹ onimọ nipa ayika sọ pe iru igbesẹ ile ẹjọ yii ni yoo maa jẹ kawọn eeayan tun maa hu iru iwa yii sii.

Wudu ni ‘’awa o le maa ṣe wahala lati mu awọn ọdaran to n ji nnkan gbe nibi ki ile ẹjọ maa dawọn silẹ, o jẹ ohun to n dun eeyan gan an.’’

Amọ lori iṣẹlẹ eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ, Wudu awọn alaṣẹ yoo gba awọn ẹṣọ eleto abo sii lati le maa sọ ibi isinku naa daadaa.

Bakan naa ni o sọ pe awọn yoo tun ṣe atunṣe ina oju popo to wa lagbegbe naa.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn alaṣẹ n gbero lati maa gbowo diẹdiẹ lọwọ awọn to sin oku ẹbi wọn sibẹ lati le maa ṣe itọju itẹ oku ọhun.