Wo àwọn olóṣèlú tí ayé ń fojú sí lára fún ipò igbákejì gómìnà l’Ondo?

Aworan Gomina Lucky aiyedatiwa ati ibeere

Oríṣun àwòrán, Hon. Lucky Orimisan Aiyedatiwa/Facebook

Kete ti wọn bura wọle fun Lucky Aiyedatiwa gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ondo lawọn eeyan ti bẹrẹ si nii beere ẹni ti yoo jẹ igbakeji rẹ.

Aiyedatiwa funra rẹ lo jẹ igbakeji fun Gomina Oluwarotin Akeredolu titi to fi di oloogbe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023.

Aiyedatiwa ni wọn bura wọle fun ni irọlẹ ọjọ naa ni ibamu pẹlu ofin orilẹede Naijiria to wi pe ipo adari ko gbọdọ ṣofo.

Ẹni ti Aiyedatiwa yoo yan bii igbakeji rẹ lo ti waa di ọrọ igboro nipinlẹ Ondo pẹlu bi awọn eeyan ṣe n darukọ ẹni to wu wọn lọkan lati jẹ igbakeji gomina tuntun.

Awọn ọdọ n fẹ ẹni to kunju oṣuwọn, to si lokun lapa

Aṣoju awọn ọdọ ipinlẹ Ondo ninu igbimọ iṣewadi #EndSars, Oluyemi Fasipe, lo ti wi pe ẹni ti Gomina Aiyedatiwa ba fẹẹ yan sipo igbakeji gomina ni ko jẹ ẹni ti yoo jẹ olootọ si gomina ati si ilu.

Fasipe to woye pe oṣelu idibo sipo gomina lọdun to n bọ yoo lapa lori iyansipo ọhun wi pe ẹni ti yoo di ipo igbakeji gomina mu lọtẹ yii gbọdọ jẹ akikanju, ọlọpọlọ pipe ati ẹni to ni akọọlẹ rere lọdọ awọn araalu.

Aṣoju ọdọ naa, tawọn eyan mọ si Yemi Fash, sọ fun BBC Yoruba pe ẹni ti Aiyedatiwa ba fẹẹ yan bi igbakeji rẹ gbọdọ ni gbogbo amuyẹ to fi lee kin gomina lẹyin lati pese iṣejọba to wuyi fun akoko diẹ ti wọn ni lori aleefa.

Aworan Gomina Aiyedatiwa ati Yemi Fash

Oríṣun àwòrán, @LuckyAiyedatiwa/X

‘Awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ APC yoo joko lati wo ẹni to yẹ ni igbakeji lẹyin idarọ ọjọ mẹta ti ijọba kede’

Ni ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo, Alex Kalejaiye, o ni awọn ko tii le maa sọrọ nipa igbakeji gomina bayi ayafi ti akoko idaro ti ijọba kede ba re kọja.

Kalejaye ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba wi pe “gbogbo ohun to ba dara ni awọn eeyan maa n du, amọ awọn agba ẹgbe yoo joko lati fi oju ṣunukun woo lẹyin akoko idaro yii.

“Oriṣiriṣi ẹgbẹ lo maa dide lati wi pe awọn n fẹ igbakeji gomina, amọ a maa wo ẹni ti a maa mu ti ko nii pa gomina, ijọba, ẹgbẹ oṣelu wa abi ilu lara.

“Ẹ ma gbagbe pe idibo gomina n bọ lọdun to n bọ, nitori idi eyi, a ni lati ṣe ohun ti yoo mu ki iṣọkan wa laarin ẹgbẹ, ti yoo si dun mọ awọn araalu ninu nitori pe awọn araalu naa lo maa dibo ti akoko ba to, a ko si gbọdo ko iyan wọn kere.

“Awa naa ti n gbọ ohun tawọn eeyan n sọ laarin ilu bi awọn kan ṣe n sọ pe musulumi abi ẹni bayi lawọn n fẹ.

“Ohun ti awọn agba ẹgbẹ ati gomina tuntun ba maa fẹnuko si yoo jẹ ohun ti yoo tẹ ọpọ ero lọrun nitori ko sẹni to lee tẹ gbogbo aye lọrun.”

‘Ọrọ igbakeji kọ lo ba gomina bayii’

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si akọwe iroyin ti Gomina Aiyedatiwa ṣẹṣẹ yan, Ọmọọba Ebenezer Adeniyan, o wi pe ọrọ yiyan igbakeji ko tii si niwaju gomina naa bayii.

Adeniyan wi pe idaro gomina to papoda ni ijọba n ṣe lọwọ ti wọn ko si tii raye ohun miran.

Akọwe iroyin naa fi kun pe ti Aiyedatiwa ba pari idaro ọga rẹ tẹlẹ ni yoo to raye lati ronu ẹni ti yoo jẹ igbakeji fun un.

Aworan Aiyedatiwa ati Akeredolu nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Hon. Lucky Orimisan Aiyedatiwa/Facebook

Yiyan igbakeji gomina yoo nilo arojinlẹ – PDP

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Peretei, ninu ero ti rẹ wi pe Aiyedatiwa yoo nilo arojinlẹ gidi lati lee yan igbakeji rẹ.

Peretei lakoko to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ wi pe “ibeere pọ ti gomina ni lati dahun funra rẹ ko too le yan igbakeji. Lara awọn ibeere naa ni pe ‘Se ki igbakeji o wa lati ẹkun idibo Akeredolu ni, lati fi lee tu wọn loju lori iku ọmọ wọn? Abi ki igbakeji o wa lati ẹkun aringbungbun to ti maa n wa ti gomina ba wa lati ẹkun guusu?’ Atawọn ibeere miran.

“Awọn ohun to n ṣẹlẹ ki Aiyedatiwa too di gomina naa yo lapa lori yiyan ẹni ti yoo jẹ igbakeji, bo tilẹ jẹ pe mi o si ni aaye ti mo fi lee da si yiyan igbakeji fun gomina tuntun naa.

“Oriṣiriṣi orukọ lawọn eeyan ti n da nigboro, bii Razaq Obe to jẹ kọmiṣọna labẹ Akeredolu to si duro ṣinṣin lẹyin Aiyedatiwa lakoko to n foju wina iyọnipo.

“Bakan naa lawọn kan n darukọ Abena (Sunday Abegunde), amọ bo ti le wu ko ri, Aiyedatiwa lo lẹtọ lati yan ẹni to wuu lati jẹ igbakeji rẹ.

Bi ipinlẹ Ondo ṣe n daro Gomina Akeredolu pẹlu ikede ọjọ mẹta latẹnu Gomina Aiyedatiwa, awọn onwoye oṣelu lo n wo ara ti gomina tuntun naa yoo daa larin oṣu mẹrin ti yoo mu ko lee di oludije ẹgbẹ oṣelu rẹ loṣu kẹrin ọdun to n bọ ti idibo abẹle ẹgbẹ naa fun idibo gomina lọdun 2024 yoo waye.

Igbagbọ awọn onwoye oṣelu yii si ni pe ẹni ti gomina ba yan bi igbakeji rẹ yoo nipa lori ijawe olubori rẹ ninu idibo abẹle ọhun.