Wọ́n sọ ọkùnrin alápatà ẹ̀ràn ní òkúta pa ‘nítorí pé ó bú Anabi’

Ọkunrin ti wọn lẹ ni okuta pa

Oríṣun àwòrán, Sani Isa

Ọkunrin alapataa ẹran kan, Usman ti padanu ẹmi rẹ lẹyin ti awọn eeyan kọ sọ ọ ni okuta pa niluu Sokoto “nitori pe o sọrọ odi si anabi”.

Ọgbẹni Usman Buda to jẹ alapata ẹran ninu ọja Dankure niluu naa ni iroyin sọ pe ariyanjiyan waye laarin oun ati awọn oniṣowo ẹgbẹ rẹ lowurọ ọjọ Aiku.

Iroyin sọ pe igun ẹsin Islam ti ẹni kọọkan wọ̀n n ṣe lo fa wahala naa, lasiko ti Usman n gbiyanju lati salaye fun awọn akẹẹgbẹ rẹ ọhun pe Ọlọrun nikan ni eeyan le gbadura si tabi bẹbẹ fun nnkan lọwọ rẹ.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ na ṣoju rẹ, Sani Isah sọ fun BBC pe o ti le ni ogun ọdun ti oun ti mọ oloogbe Usman , ti oun si mọ ọ gẹgẹ bi eeyan daadaa ti kii fi ẹsin rẹ ṣere rara.

O ni “awọn eeyan kan lo wa sinu ọja lati tọrọ owo. Nibi ti Usman ti n

Salaye fun wọn pe Allah nikan lo yẹ ki eeyan ma a tọrọ lọwọ rẹ, ni inu ti bi awọn eeyan naa pe nnkan to sọ ko dara.

“Aigbọra ẹni ye ti ko yẹ ko fa ija rara lo da wahala to yọri si iku rẹ.”

Ọjọ aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn eeyan kan ṣe n sọ Usman ni okuta pa, ti wọn si n pariwo ‘Allahu Akbar’.

Ẹlomiran to tun mọ oloogbe naa sọ pe awọn iyawo ati ọpọlọpọ ọmọ ni Usman fi silẹ saye lọ, ti wọn si wa ninu ibanujẹ nitori ohun to ṣẹlẹ si olori ile wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii n lọ lọwọ

Lori iṣẹlẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ sokoto ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Wọn ni ni nnkan bi aago mẹsan-an kọja ogun iṣẹju ni owurọ ọjọ Aiku, ni awọn gba ipe pajawiri nipa nnkan to ṣẹlẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa, ASP Ahmad Rufa’i sọ ninu atẹjade kan pe ni kia ti awọn gba ipe naa ni kọmisanna ọlọpaa, ati ọga ọlọpaa agbegbe Kwanni, ko awọn ọlọpaa lọ sinu ọja naa.

“Nigba ti a de ibẹ, awọn eero to n lẹ Usman ni okuta salọ kuro nibẹ, ti wọn si fi silẹ sibẹ. Lati ibẹ la ti gbe e lọ sileewosan Usmanu Danfodio Teaching Hosspital niluu Sokoto, ṣugbọn o pada kú.”

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe iwadii ti n lọ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn apaayan naa.

Iru iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si akẹkọọ kan nipinlẹ Sokoto

Ọdun 2022 ni iroyin iru iṣẹlẹ bayii tàn kaakiri agbaye, nigba ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ ikọṣẹ olukọ niluu Sokoto, sọ okuta pa akẹkọọbinrin kan, Deborah Yakubu nitori ẹsun kan naa.

Ni owurọ ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ni awọn akẹkọọ naa wọ Deborah jade si ita gbangba lati inu yaara rẹ, fun ẹsun pe o sọrọ odi si anabi ni oju opo Whatsapp.

Lẹyin naa ni wọn lẹ ẹ ni okuta pa, ki wọn o to dana sun oku rẹ.