Ilé ẹjọ́ sọ Trinity Guy sí àtìmọ́lé ọgbà ẹ̀wọ̀n bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe ń tẹ̀síwájú

Trinity Guy

Oríṣun àwòrán, iamtrinityguy

Ile ẹjọ Majistreti to n gbọ ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan alawade ori ayelujara, Trinity Guy, ti ni ki wọn fi afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn titi di oṣu to n bọ.

Ṣaaju ni agbẹjọro afurasi ọhun, Oludare Adebayo, ti kọkọ bẹ ile ẹjọ naa pe ko da onibara oun silẹ.

Amọ adajọ majistreti naa, PO Adetuyibi, kọ ẹbẹ rẹ latari pe wọn ti ṣi ẹjọ kan ni ọọfisi ijọba to n ri si eto idajọ nipilẹ Oyo nipa afurasin naa.

Yatọ si Trinity Guy ti ile ẹjọ ni ko lọ lọgba diẹ ninu ẹwọn, ile ẹjọ tun sọ pe ki iya ati baba ọmọ ọdun mẹwaa to wa ninu fidio Trinity Guy wa ni atimọle ninu ẹwọn.

Gẹgẹ bii ohun ti adajọ sọ, awọn obi ọmọ naa ṣe ohun to lodi labẹ ofin bi wọn ṣe fi ọmọ wọn silẹ lati lati ṣe irufẹ fidio to ṣe pẹlẹ afurasi ọhun.

Triniguy wọ gau lẹyin ti fidio ibi to ti n bere awọ nnkan ọmọkunrin rẹ lọwọ ọmọdebinrin naa gba oju ayelujara kan.

Yatọ si fidio ti Trinity Guy ti lo ọmọde naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ti kọkọ n bu ẹnu atẹ lu awọn ere ti Trinity Guy maa n ṣe lori ayelujara ṣaaju akoko yii.

Adejọbi sọ pe awọn ere naa ti lagbara ju, o si yẹ ki Trinity Guy ṣọra fun irufẹ ere bẹẹ lawujọ, paapaa bi nnkan ṣe ni Naijiria lasiko yii.

Wayi o, ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii fun itẹsiwaju.

Trinity Guy yóò fojú ba iléẹjọ́ lónìí nílùú Ibadan

AworanTrinity Guy

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gbajugbaja alawade ori ayelujara, Abdullahi Adisa, ti ọpọ mọ si Trinity Guy ni yoo foju ba ileẹjọ loni.

Eyi waye tori fọnran kan to gbe sori ayelujara ninu eyi to ti ni ki ọmọdebinrin kan maa se apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri.

Osẹ to kọja ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ‘Trinity guy’ fara rẹ han si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ pẹlu agbẹjọro rẹ lati dahun ipe ti wọn pe e lọjọbọ.

Agbẹnusọ Ileesẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ni Trinity Guy, yoo foju ba ileẹjọ lọjọ Aje lori fọnran kan to fi sori ayelujara ninu eyi to ti n ni ki ọmọdebinrin kan maa ṣe apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri.

Atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Oṣifẹsọ fi sita lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni pe lẹyin ijiroro ọlọpaa ati Trinity guy, awọn ti lọ fi ṣinkun ofin mu baba ati iya ọmọ naa, Isiaka Ahmed ati aya rẹ Rofiat.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, trinity guy ṣalaye fun awọn ọlọpaa to fi ọrọ waa lẹnu wo pe, oun gba aṣẹ lọwọ awọn obi ọmọdebinrin naa ki oun to lo o fun fidio naa, ati ki oun to gbe e si ori ayelujara.

Ninu ifọrọwerọ to wa ṣe pẹlu BBC News Yoruba, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ naa sọ pe gbajumọ alawada oriayelujara naa, sọ pe oṣu kọkanla ọdun 2022 ni oun fi fido naa sita.

O ni ko pẹ pupọ ti oun gbe fidio naa sita ti oun tun yọọ kuro nigba ti ariwo dide tako o paapaa lori aitọ rẹ pẹlu ọrọ ọmọde.

Ṣaaju eyi yii ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọga Ọlọpaa Olumuyiwa Adejọbi ti kọkọ ke si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn ti ọwọ Trinity guy bọṣọ pẹlu ọkan o jọkan fidio alawada, skit to n ṣe eyi to sọ pe o lodi si ẹtọ ọmọniyan ati alafia ilu