Ààrẹ Bio ló ń m’ókè nínú èsì ìdìbò tí àjọ elétò ìdìbò Sierra Leone ti kéde

Maada Bio

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alaga ajọ eleto idibo ni orilẹ-ede Sierra Leone, Mohamed Konneh, ti kede diẹ lara esi idibo aarẹ to waye ni orilẹ-ede naa lọjọ Abamẹta.

O ni ida ọgọta (60%) ni esi to ṣi wa nilẹ.

Ninu esi to kede, oludije ẹgbẹ SLLP, Aarẹ Julius Maada Bio lo n le waju pẹlu ibo 1, 067, 666, oludije APC, Kamara Samura n ṣe ipo keji pẹlu ibo 793, 751.

Ajọ eleto idibo naa sọ pe oun yoo kede esi to ku laarin wakati mejidinlaadọta.

Ṣaaju ni Ọgbẹni Konneh sọ fun awọn akọroyin pe ọna ti ko mu magomago dani ni awọn n gba ka esi ibo naa loju awọn aṣoju ẹgbẹ osẹlu, awọn akọroyin ati awọn alamojuto kaakiri agbaye.

Ibi yìí ni nǹkan dé dúró níbi ètò ìdìbò Sierra Leone

Aworan

Kika esi ibo aarẹ lorilẹede Sierra Leone si n tẹsiwaju lẹyin ọjọ meji ti eto idibo naa waye.

A ko ti le sọ pato ẹni to n lewaju ninu eto idibo aarẹ laarin Aarẹ Julius Maada bio ati alatako rẹ, Samura Kamara sugbọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ni sọrọ sita pe awọn ni awọn bori ibo naa.

Awọn awoye eto idibo lati ilẹ okere ti wa pe fun alaafia , ki wọn eeyan si duro esi ibo lati ajọ eleto idibo sugbọn ọpọ lori kọminu lori bi wọn ko se ti kede esi ibi sita.

Ajọ European Union ti wa rọ ajọ eleto idibo pe ki wọn pese ọna otitọ ti wọn fi ka eto idibo naa sita lati le fi ọkan awọn eeyan orilẹede naa balẹ.

Ẹni to ba bori eto idibo naa gbọdọ ni ida marunlelaadọta ibo, a jẹ bẹ eto idibo naa yoo jẹ tuntun se laarin awọpn oludije meji lo ibo to pọju.

Lọjọ Aiku, Ileeṣẹ ologun ati ileeṣẹ ọlọpaa se ọfisi ẹgbẹ oṣelu Kamara ni bi apero kan to waye ni Freetown, ti wọn si fẹsun kan wọn pe wọn sian bolẹ ni ọfisi ẹgbẹ oselu alatako

Kamara ninu ọrọ to fi si ori Ayelujara ni, “Wọn yin ibọn mọ ọfisis mi.”

Gẹgẹ bi Reuters se sọ, obinrin kan ni o selese yanayana, ti ko si gba itọju. Nnkan to sẹlẹ si ni ko ti di mimọ/ Ileeṣẹ ọlọpaa ko ti sọrọ lori isẹlẹ naa.