Wọ́n bá òkú ọ̀gá ọlọ́pàá nínú ilé rẹ̀ l‘Ogbomoso, ariwo sọ!

Gbolahan Oyedemi

Oríṣun àwòrán, Leadership

Níṣe ni àwọn ènìyàn ìlú Ogbomoso, ìpínlẹ̀ Oyo ń kọ ah! Ah! ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, bí wọ́n ṣe bá òkú igbákejì kọmíṣánnà ọlọ́pàá ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko, Gbolahan Oyedemi nínú ilé rẹ̀.

Oyedemi ló ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olórí ẹ̀ṣọ́ àwọn ọlọ́pàá fún gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Oyo, olóògbé Alao Akala lọ́dún 2006.

Olóògbé Oyedemi tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ogbomoso, ṣàbẹ̀wò sí ìlú náà láti ṣayẹyẹ ọdún àjíǹde lópin ọ̀sẹ̀.

Àwọn ará àdúgbò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sọ fun àwọn akọ̀ròyìn pé, wọ́n ṣàdédé bá òkú ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá náà nínú ilé tó ń mì jolojolo.

Èyí ló ń mú kí àwọn èèyàn máa rò ó wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

Oyedemi ń gbé pẹ̀lú ìyá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ilé tó kọ́ ní agbègbè Randa, kó tó kó lọ sí ilé mìíràn tó kọ́ si Federal Lowcost area, níbi tó kú sí

Wọ́n ṣàlàyé pé Oyedemi àtàwọn abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ ni wọ́n jọ wọ ìlú Ogbomoso àmọ́ tó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa lọ sílé wọn láti lọ ṣọdún.

Ọlọ́pàá mìíràn tí òun àti Oyedemi jọ ṣiṣẹ́ lábẹ́ àkóso Akala ní ó ya àwọn lẹ́nu láti gbọ pé Oyedemi jáde láyé lẹ́yìn tó lọ sílé lọ ṣọdún.

Ohun tí a gbọ́ ni pé Oyedemi ló ń gbé pẹ̀lú ìyá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ilé tó kọ́ fún ìyá náà ní agbègbè Randa kó tó di wí pé ó kó lọ sí ilé mìíràn tó kọ́ sí òpópónà Petros Academy Street, Federal Lowcost area níbi tó kú sí.

Àwọn kan ń sọ pé Oyedemi kò ní ìyàwó títí tí ọlọ́jọ́ fi dé.