Ọgbẹ́ ọkàn mú áwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ Chibok torí bí wọn ṣe fẹ́ ajínigbé pẹ̀lú àtìlẹyìn ìjọba

Jinshai Yama

Oríṣun àwòrán, PRNigeria.com/BBC

Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram jí ọmọ Yama Bullum gbé ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Chibok, ó ní òun tí ti pàdánù ọmọ náà lẹ́ẹ̀kan si.

Ọmọ Yama Bullum, Jinkai Yama wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin 276 tí àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram jígbé ní ilé ẹ̀kọ́ girama kan ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin ọdún 2014 ní ìlú Chibok, ìpínlẹ̀ Borno.

Mẹ́tàdínlọ́gọ́ta nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà rí bi bọ́ lọ́wọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí ọ̀hún.

Láàárín ọdún 2016 sí 2018, iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 108 gbà kalẹ̀ nínú wọn, tí àwọn 91 sì wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé láti ìgbà náà.

Jinkai Yama jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok ogun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Borno gbà kalẹ̀ kúrò nínú igbó Sambisa láàárín ọdún méjì sẹ́yìn.

Àmọ́ inú bàbá rẹ̀ kò dùn pé Jinkai pinnu pé òun fẹ́ wà pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn agbéṣùmọ̀mí tó ji gbé, tó sì ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú.

“Inú mi kò dùn sí ìgbésẹ̀ ìjọba tó fi ọmọ mi lọ́kọ, ìyá rẹ̀ ń bínú gidi”

Ní ìlú Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Borno ní ilé ìgbé tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Babagana Umaru Zulum pèsè ni àwọn tọkọtaya náà ń gbé.

“Inú mi kò dùn sí ìgbésẹ̀ ìjọba yìí. Àwọn ọmọbìnrin yìí jàjà móríbọ́ kúrò ní àháma àwọn ajínigbé, ìjọba sì tún fi wọ́n lọ́kọ. Ìyá rẹ̀ ń bínú gidi.” Bàbá Bullum sọ.

Ó ní òun mọ̀ nípa ìgbéyàwó ọmọ òun nígbà tó pe òun nínú oṣù Kẹjọ, tó sì ní kí òun bá ọkọ òun tó jẹ́ agbéṣùmọ̀mí náà sọ̀rọ̀.

Kó tó di ìgbà náà, Bullum ní òun rò pé ọmọ òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta wà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Chibok yòókù tí wọ́n jọ dóòlà ni.

Gẹ́gẹ́ bí òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok míì, Bullum ń kọminú lórí ohun tó fara jọ pé ìjọba Nàìjíríà ń fọwọ́ sí ìgbéyàwó láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà àtàwọn tó jí wọn gbé.

Àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní níṣe ló dàbí ẹni pé gómìnà Zulum lo àwọn ọmọ àwọn láti lè rí pé àláfíà jọba nínú ìlú nípa fífi wọ́n sílẹ̀ láti máa gbé pẹ̀lú àwọn tó jí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, tí ìjọba sì tún ń pèsè ilé fún wọn.

Púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé náà ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Krístẹnì.

Àwọn òbí Jinshai

Oríṣun àwòrán, Yama Bullum

Ọ̀pọ̀ èèyàn ní Chibok ń bèèrè pé kí ló dé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń ṣe ẹ̀sìn Islam lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé wọn?

Ìròyìn nípa bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣì ṣe wà nínú ìgbéyàwó pẹ̀lú àwọn tó jí wọn gbé yìí tún ń pòruru ọkàn àwọn òbí tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn ní dandan láti darapọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Islam.

Alága ẹgbẹ́ àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ Chibok, Yakubu Nkeki ní ọ̀pọ̀ èèyàn ní Chibok ló ń bèèrè pé kí ló dé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣì ń ṣe ẹ̀sìn Islam lẹ́yìn tí wọ́n ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé wọn.

Gómìnà Zulum ní òun tó jẹ òun lógún ni pé àwọn ọmọbìnrin náà kò padà sínú igbó tí wọ́n ti gbà wọ́n sílẹ̀.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló ní àwọn kò ní kúrò nínú igbó Sambisa àyàfi tí ìjọba bá gba àwọn láàyè láti kúrò pẹ̀lú àwọn ọkọ àwọn.

Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà ni Aisha Graema tó sọ fún akọ̀ròyìn BBC pé òun kò bá ti má kúrò nínú igbó náà tó bá jẹ́ pé ọkọ òun, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbéṣùmọ̀mí náà, kò ní tẹ̀lé òun.

Lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n jí wọn gbé ni Aisha Graema ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ náà.

“Ọdún mẹ́jọ rèé lá ti ṣe ìgbéyàwó,” Aisha tó ti bí ọmọ mẹ́ta sọ.

Aisha Graema

Oríṣun àwòrán, AFP

Nígbà tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí ló dé tí wọ́n fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn tó ba àyé wọn jẹ́, wọ́n ní ohun tó wà nídìí rẹ̀ kò lè yé mi – Kọ̀misana

Aisha Graema ní òun ni òun kọ́kọ́ kúrò nínú igbo kí ó tó wá bá òun àti pé nítorí àwọn kò ní ẹbí àti ara nínú igbo tí àwọn wà ní àwọn ṣe pinnu láti jáde.

Ó fi kun pé lẹ́yìn tí ọkọ òun ṣe àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ ni ìjọba tó gbà kí àwọn máa gbé papọ̀, tí wọ́n ń fún àwọn ní oúnjẹ àti ilé láti máa gbé.

Ìbúgbe àwọn alálàájì tó wà ní Bulumkutu ni ààyè tí ìjọba Borno ń lò láti fi máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ikọ̀ Boko Haram tó bá ti pinnu láti juwọ́ lẹ̀ fún ìjọba.

Lẹ́yìn tí wan bá ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn àtúnṣe fún wọn tán ni wọ́n máa ń darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn àwùjọ ní ilé ìgbé tí ìjọba pèsè.

Gómìnà Zulum ní èèyàn 160,000 ni wọ́n ti wà nínú ilé yìí.

Kọmíṣánnà fọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ìdàgbàsókè àwùjọ ní ìpínlẹ̀ Borno, Zuwaira Gambo ní àwọn obìnrin náà ló yarí pé àwọn fẹ́ fẹ́ àwọn ọkọ àwọn ní dandan, pé kìí ṣe ijọba ló kàn wọ́n nípá.

Gambo ní nígbà tí òun bèèrè lọ́wọ́ wọn pé kí ló dé tí wọ́n fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn tó ba àyé wọn jẹ́, wọ́n ní ohun tó wà nídìí rẹ̀ kò lè yé òun.

Awọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok àtàwọn ọmọ wọn ninu ile ti ijọba kọ fun wọn

Oríṣun àwòrán, Yakubu Nkeki

Ìjọba kò ṣètò tó yẹ kalẹ̀ fáwọn ọmọbìnrin ọ̀hún ló fa gbogbo ohun tí àwọn ọmọbìnrin náà ń sọ – Ajijagbara

Àwọn obìnrin ogún àtàwọn ọmọ wọn mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni ìjọba kó kúrò nínú igbó lọ sí ilé tí wọ́n kọ́ fún wọn ní Maiduguri pẹ̀lú àwọn ọkọ wọn méje.

Ìjọba ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún wọn lórí ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọwọ́ bíi aṣọ rírán àti ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọ̀mpútà.

Gómìnà Zulum ní òun gbàgbọ́ pé ṣíṣe àwọn nǹkan yìí fáwọn ọmọbìnrin náà yóò mú káwọn mìíràn tó wà nínú igbó náà tún jáde síta.

Nkeki ní òun kò mọ ohun tí òun yóò só lórí nǹkan tí òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń fẹ́ àti ìfẹ́ àwọn ọmọbìnrin náà.

Ó ní àwọn ọmọbìnrin ọ̀hún sọ f;un òun pé àwọn kò lè gbé láìsí pẹ̀lú àwọn ọkọ àwọn, àmọ́ òun ń fẹ́ kí wọ́n kúrò nínú igbo Sambisa tí wọ́n wà.

Aisha Muhammed-Oyebode tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó já fùn ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tí wọ́n jí wọn gbé ní ìjọba kò ṣètò tó yẹ kalẹ̀ fáwọn ọmọbìnrin ọ̀hún ló fa gbogbo ohun tí àwọn ọmọbìnrin náà ń sọ.

Jinkai Yama kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ mọ́, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá pè é ló jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ ló máa ń gbé ìpè náà.

Ó sọ fún akọ̀ròyìn BBC pé òun kò ní bá a sọ̀rọ̀ àti pé ìbáṣepọ̀ àárín òun ài àwọn ẹbí òun kò kan ẹnikẹ́ni.

Bákan náà ló ní ìjínigbé òun ló mú òun mọ̀ nípa ẹ̀sìn tí òun ń ṣe báyìí.

Inú bàbá rẹ̀ k]o dùn pé ọmọ àwọn kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn mọ́.