Àwọn agbébọn jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé ní mọ́ṣálásí, jí ọmọdé 30 míì níbòmíì

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní alẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹrin ọdún 2024 ni àwọn ajínigbé tún dá bírà ní mọ́ṣáláṣí kan ní ìlú Gusau, ìpínlẹ̀ Zamfara, níbi tí wọ́n ti lọ jí ọ̀pọ̀ àwọn olùjọ́sìn gbé lọ lásìkò tí wọ́n ń yan nọ́fílà òru lọ́wọ́.

Tí àwẹ̀ Ramadan bá ti kú mẹ́wàá ìgbẹ̀yìn ni àwọn èèyàn máa ń yan nọ́fílà lóru láti pọn kún ìjọ́sìin wọn.

Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ kan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé lásìkò tí àwọn ènìyàn náà ń kírun lọ́wọ́ ni àwọn agbébọn náà yawọ mọ́ṣálásí ọ̀hún, tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kírun gbé lọ.

“Àwọn ajínigbé kò ì tíì bèrè ohunkóhun fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé”

Ó ní òun kò lè sọ pé iye kan báyìí pàtó ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jí àmọ́ tó ní àwọn aláṣẹ ń ṣiṣẹ́ láti ṣàwárí àwọn ènìyàn náà.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àwọn ajínigbé náà kò ì tíì bèrè ohunkóhun tàbí iye kankan láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n jí gbé.

Bákan náà ni kò ì tíì sí ikọ̀ kankan tó jáde síta láti sọ pé àwọn ni àwọn wà nídìí ìkọlù ọ̀hún.

Ìkọlù yìí ló ń wáyé bí àìsí ààbò ṣe ń peléke si ní ìpínlẹ̀ Zamfara àti káàkiri Nàìjíríà. Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni gómìnà Dauda Lawal ṣe àbẹ̀wò sí ààrẹ Tinubu lórí ìpèníjà ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ náà.

Àwọn tún jí ọmọdé ọgbọ̀n gbé ní Katsina

Nínú ìròyìn míì, àwọn agbébọn tún jí àwọn ọmọdé ọgbọ̀n ní ìlú Kasai, ìjọba ìbílẹ̀ Batsari, ìpínlẹ̀ Katsina.

Ìjọba ìbílẹ̀ Batsari ló jẹ́ mímọ̀ fún àwọn ìwà ọ̀daràn àti ìjínigbé, tó sì ń fi ojoojúmọ́ peléke si.

Gẹ́gẹ́ bí olùgbé agbègbè náà ṣe sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Channels TV ní àwọn ọmọdé táwọn ajínigbé náà jí gbé ni wọ́n lọ sí ẹnu odi ìlú láti lọ ṣẹ́ igi fún àwọn òbí wọn kí wọ́n tó kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà.

“Àwọn afurasí ajínigbé dá àwọn ọmọ náà lọ́nà lásìkò tí wọ́n lọ ṣẹ́gi tí àwọn òbí wọn má fi dáná fún wọn.”

Kò sí ẹni tó mọ ohun tó fa ìjínigbé náà, tí àwọn ajínigbé náà kò sì tíì kàn sí àwọn òbí ọmọ náà láti bèrè ohunkóhun.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àwọn aláṣẹ àti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò sọ̀rọ̀ lórí ìjínigbé yìí, táwọn ènìyàn ìlú náà sì ń ní ìrètí pé àláfíà yóò jọba ní agbègbè àwọn láìpẹ́.