Wo ọ̀nà mẹ́wàá tí o fi lè dábò bo ara ré lásòkò ọyẹ́ yìí

Akoko ọyẹ jẹ akoko kan ti awọn ọmọ Naijiria maa n reti lati oṣu Kọkanla titi di aarin oṣu Kẹta ọdun keji.

Akoko naa jẹ asiko ti atẹgun maa n fẹ lati iha Ariwa ila oorun, tabi lati ila oorun si iwọ oorun Sahara.

Oniruru orilẹ-ede lo ni akoko ti oju ọjọ wọn maa n yipada, fun apẹrẹ, lawọn agbegbe kan Yuroopu, yinyin maa n jabọ lati oju ofurufu.