Wo ọ̀nà mẹ́fà láti dènà ìkọlù ejò afàyàfà bí o ṣe ń lo ìsinmi ọdún Kérésìmésì yìí ní abúlé rẹ

Ejo

Oríṣun àwòrán, @Others

E ku ewu ọdun Keresimesi ati ti ọdun tuntun ni ọpọ n kira wọn lasiko yii ni ọpọ rinrinajo lo si abule ati ẹyin odi lati lọ ṣe ọdun pẹlu ẹbi, ara ati iyekan wọn.

Bakan naa ni awọn eeyan tun n fi sori ayelujara pe o ṣeeṣe ki ọpọ ejo afayafa maa jade wa ya oorun nitori ọyẹ to gbode kan lasiko yii.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba se akojopó ọna mẹfa ti ejo ko ṣe ni le bu ọjẹ lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii.

Ọna akọkọ ni ki eniyan ri pe ile igbọnsẹ tabi baluwe ko famimọra tabi dẹrun fun ejo lati wọle si inu rẹ

  • Ri pe gbogbo ferese ati ilẹkun baluwe lo n wa ni titi ni gbogbo igba ki ejo ma ba a rapala wọ inu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Ri wi pe o ko gba eku tabi ekute ile ni aaye lati ma a ṣere tabi dagba ni inu ile rẹ, nipa lilo awọn oogun to n koju awọn eku ninu ile, nitori ejo ma n tẹle ibi ti ounjẹ ba ti wa, ijẹ wọn si ni eku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Ri daju pe ko si igbo tabi idọti ni agbegbe ile, ki wọn si ma a jo awọn igbo, ki ejo tabi ohun afayafa miran ma lugọ si ibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Bakan naa ni o dara lati fin agbegbe, to fi mọ ile igbọnsẹ ati baluwẹ rẹ loore koore.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Ri pe o de ohun igbọnsẹ rẹ nigba kugba ti o ba ti lo o tan, to fi mọ baluwẹ naa ki awọn ẹranko tabi ohun afayafa ma ri aye wọ inu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Ni afikun, ri pe o wo inu ile igbọnsẹ rẹ to fi mọ WC rẹ daradara, ki o to joko lee,ma si lo ile igbọnsẹ ninu okunkun lai ri pe o wo finifini, ki o to lo o lai fi gbogbo ara gbe idi lee.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Saaju ni iroyin jade losu kan seyion lori ọrọ ejo.

Pẹlu bi iroyin ṣe gbode kan lori bi ejo ṣe n dede wọ inu ile awọn eeyan tabi ki awọn eeyan dede ri ejo ko yọju lati inu ile igbọnsẹ wọn lo mu ki awọn eeyan maa beere ibeere ohu to yẹ lati ṣe bi ejo ba ṣa eeyan jẹ ati bi wọn ṣe lee dena rẹ.

Ko si ẹni to lee mọ idi ti ejo fi wa ọna rapala wọ inu ile igbọnsẹ.

Oṣiṣẹ awọn ọpa paipu to wọ inu ile ti BBC ba sọrọ to maa n ba awọn eeyan ṣiṣẹ inu yara igbọnsẹ sọ pe ọpọlọpọ eeyan lo maa n ro pe paipu to jade lati inu ile igbọnsẹ maa n ni omi ninu amọ o ni ko ri bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ọna bi wọn ṣe ṣe koto igbọnsẹ ni pe inu rẹ nikan ni omi maa n wa ati pe igba ti omi maa n wọ inu paipu ni igba ti eeyan ba tẹ omi lati ṣan igbẹ danu lẹyin teeyan ba ya igbẹ tan”.

O tun sọ pe lara ọna kan ti ejo fi maa n wọ inu paipu ile igbọnsẹ ni yala lati inu tanki to wa ni ita tabi inu “soakaway” ti igbẹ ati itọ n lọ to ba ti fọ nibi kan tabi ti alafo kan ṣi silẹ fun ejo lati wọle.

Gẹgẹ bi eyi ṣe wa n kọ awọn eeyan lominu bi ejo ṣe n san awọn eeyan ni adugbo wọn, ajọ isọkan agbaye, WHO ti n fi awọn imọran sita lori ohun to yẹ keeyan ṣe bi iriri yii ba ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ohun to yẹ koo ṣe bi ejo ba san eeyan

– Gbe eeyan naa kuro nibi ti ejo ti san an tabi ki o le ejo naa kuro to ba ṣi yọju.

– Yọ ohun kohun to ba le dain kuro ni oju ibi ti ejo ti bu ni naa jẹ – nkan bii oruka tabi ẹgba ọwọ tori o lee da wahala mii silẹ bi oju sisan yẹn ba wu.

– Jẹ ki ẹni naa fi ara balẹ tori kii ṣe ọpọlọpọ gbogbo ejo sisan naa ni yoo fa iku ẹni naa loju ẹsẹ.

– Ma jẹ ki ẹni naa gbera rara, iwọ ni koo gbe ẹni naa lọ si ile ibudo ilera kia kia.

– Tẹ oju egbo ti ejo san naa pẹlu agbara

– Ma ṣe lo oogun ibilẹ.

– Ẹni naa le lo oogun oyinbo Paracetemol lati din ara riro ku tori bi ejo ba san ni jẹ, o maa n dun eeyan gidi gan.

– Yi oju ni naa si ẹgbẹ tori ti o ba fẹ bi eebi.

– Rii daju pe o n woo pe ẹni naa ṣi n mi

Bi o ṣe le pa ile igbọnsẹ rẹ mọ kuro lọwọ ejo

Ejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rii daju pe ina wa ni titan nigba ti o ba fẹ lo ile igbọnsẹ ki o le wo inu koto igbọnsẹ wo koo to gbe idi lee.

Ma sọ ile igbọnsẹ rẹ di ibi ikẹru si – rii pe o n wa ni mimọ toni toni ni gbogbo igba.

Lẹẹkọọkan, maa ṣe ayẹwo paipu, “soakaway”, iho salanga, inu orule, ogiri to ba ni iho tabi to ba la tabi awọn nkan to ni ọmọri to ti ṣi silẹ. Ṣe atunṣe wọn lọgan ti o ba ti ri wọn.