Mọ̀ síi nípa àwọn Obìnrin tó wà láyé Ooni Ogunwusi ṣáájú Olòrì Naomi SilekunOla

Ooni

Oríṣun àwòrán, Others

Eyi lo jẹ ki BBC Yoruba lọ ṣe iwadii awọn irpyin to n kede ọpọlọpọ obinrin fun Ooni naa pe wọn jẹ aya rẹ yatọ si Olori Naomi.

Opọ ninu awọn iroyin naa jẹ ofege nitori ko si akọsilẹ to ṣe e fihan pe nitootọ ni kabiesi Ogunwusi fẹ awọn obinrin mẹwaa naa ti ọpọ n sọ nipa wọn lori ayelujara.

Obinrin mẹrin wọnyii nikan ni akosile ojutaye wa nipa wọn ati akoko ti wọn fi wa pẹlu Ojaja keji.

Obinrin akọkọ ti igba oju mọ pẹlu Oba Adeyeye Ogunwusi ni arabinrin Omolara Olatubosun.

Odọmọde ti ko tii pe ẹni ogun ọdun ni awọn mejeeji lasiko ti wọn jọ n rin papọ ki o to di oyun ti wọn fi bi Ọmọbabinrin Adeola Ogunwusi ni o din diẹ ni ọgbọn ọdun seyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Adebukola Bombata ni obinrin imii to jade ninu aye Oba Ogunwusi ṣaaju ki o to jẹ Oba Ile Ife.

Lọdun 2008 ni wọn ṣe igbeyawo ni won jọ gbe papọ ki onikaluku to pin gaari.

Ooni ati Adebukola

Oríṣun àwòrán, @Others

Bi awọn kan ṣe sọ pe Adebukola fi Ooni Ogunwusi silẹ lọdun 2015 nitori pe ipo Oba naa ko wu u ni àwọn mii ni pe nkan miran lo jẹ ki wọn fi ara wọn silẹ.

Lọdun 2015 lẹyin ti Ooni gori aleefa itẹ awọn baba nla rẹ ni o gbiyanju iyawo miran.

Ooni ko duro nile Yoruba rara lati lọ mu arẹwa to wu Kabiesi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Benin ni ipinlẹ Edo to jẹ ọmọ iya Oodua ni Oba Ogunwusi ti lọ gbe Olori Zainab Otiti Obanor Wuraola.

Igbeyawo naa si wa sopin lọdun 2017.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lọdun 2018 ni Oba Adeyeye Ogunwusi gbe Ajihinrere obinrin Naomi Silekunola lati ipinlẹ Ondo ni iyawo.

Oba Oke fi omokunrin lantilanti, Tadenikawo Ogunwusi ta wọn lọrẹ lọdun to kọja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbeyawo yii ni Olori Naomi si wa kede lori ayelujara bayii pe oun ti sun siwaju nitori pe oun fẹ gbajumọ ṣiṣe iya ọmọ rẹ Tadenikawo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ