Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife

Olori Naomisilekunola

Oríṣun àwòrán, Queen Naomi

Iyawo Ooni Ogunwusi ti Ile Ife, Silekunola Moronke Naomi dédé ya awọn eniyan lẹ́nu ni Ọjọbọ tó kọja nigba to jade sori ayelujara lati kede pe oun ti fi àkọlé Olori ti ilu Ile Ife silẹ toun sì ti ń da ṣe iya ọmọ oun, Tadenikawo to si Olori awọn eniyan lo ku ti oun n jẹ bayii.

Silekunola Moronke ni iyawo alarede ikeji ti Alayeluwa Ọba nla nla ni ilẹ̀ Yoruba, Ooni Ile Ife yóò fẹ niṣu lọka.

Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Other

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa lo ṣàlàyé pe ọmọ tí oun bi fun Ooni ni ọmọ àkọ́kọ́ ti oun yoo bí laye oun lodi si iroyin ti awọn kan n gbe kiri.

Ko si ẹni ti ko bọ̀wọ̀ fun ipo Ooni tori igbagbọ awọn Yoruba ni pe iran Oduduwa to jẹ Orisa ilẹ̀ Yoruba ni Ooni ti ṣẹ wa. Eyi lo mu ki iyi pọ gidi fun Ooni ati iyawo rẹ.

Ẹwẹ, Olori Silekunola tun sọ ninu atejade rẹ pe ọ̀tọ̀ ni oju ti Ooni n fihan fun araye ọ̀tọ̀ to n fihan ninu ile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nípa igbeyawo Ooni ati Silekunola

Iyawo Ooni of Ile-Ife, Silekunola Moronke Naomi

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Ṣáájú ìgbéyàwó wọn lọdun 2018, Ooni fi oju olólùfẹ́ rẹ han to si ni oun ti ri aayo ọkan oun to si juwe rẹ gẹgẹ bii Woli. Asiko naa ni okiki arabinrin naa kan kaakiri agbaye tori àwọn eeyan n woye pe bawo ni Ojisẹ Ọlọhun to maa n ṣe awọn eto igbagbọ oniruuru pẹlu isẹ ami àti iyanu yoo ṣe yàn lati lọ fẹ Ọba to n b’òrìṣà to si n ṣe àṣà ilẹ̀ Yoruba.

Àmọ́ ṣá pẹlu idunu oun ayọ̀ to fi mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ ni wọn fi gbeyawo lọdun 2018.

Igbeyawo wọn ti pe ọdun mẹta bayii.

Laarin ọdun mẹta yìí, wọn ti bi ọmọ kan fun ara wọn. Lọdun 2020 ni Ooni kede pe awọn bi ọmọkùnrin ti ọmọ naa si jẹ ọkan pataki ni ilẹ̀ Yoruba. Bo tilẹ̀ jẹ pe ko tii le jẹ Ọba, òun náà jẹ Arẹmọ. Eyi túmọ̀ fun Olori Silekunola naa le di ìyá Ọba bi ọmọ rẹ ba jẹ Ọba Ile Ife.

Wòlíì

Wife of di Ooni of Ile-Ife, Silekunola Moronke Naomi

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Silekunola Naomi bẹ̀rẹ̀ isẹ ìránṣẹ́ lekunrere gẹ́gẹ́ bíi Woli lọdun 2011 to si bẹ̀rẹ̀ En-Herald Ministries nigba to wa ni ọmọ ọdun mejidinlogun.

En-Herald Ministries jẹ ìpéjọpọ to da gbogbo ìjọ pọ eyi to kalẹ si ilu Akure ni Ìpínlẹ̀ Ondo.

Ó jẹ oludari ẹ̀mí ó sì tún jẹ́ Ajihinrere tó máa ń ṣe isọji ti ero si maa n pọ.

Iroyin kan ni níbi eto adura adaṣe tìrẹ kan to lọ ṣe níbi ọkàn lára àwọn ibi igbafẹ ti Ooni kọ lo ti pade obìnrin àgbà Ojisẹ Ọlọhun kan to padà juwe rẹ fun Ooni.

Lòdì sí èyí, ninu atejade ti Olori Naomi fi sita lọjọ díẹ̀ sẹ́yìn, o ni kii ṣe obìnrin náà lo fi òun han Ooni dipo bẹẹ, o ni Ooni gan lo fi òun àti Ojisẹ Ọlọhun naa ati oun han ara awọn lẹ́yìn igbeyawo awọn ti oun si fún un ní ọwọ lati igba naa.

Olori Naomisilekunola

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Bo tilẹ̀ jẹ pe Ojisẹ Ọlọrun ni Naomi, o fara mọ gbogbo àṣà igbeyawo ti wọn ṣe fun un tori o fẹ Ooni toun funra rẹ si ṣe ohun gbogbo ti wọn ni ko ṣe.

Lara etutu iwẹnumọ to ṣe ni pe o rìn dá ẹjẹ ẹranko kọja wọ inú Ààfin gẹgẹ bi iyawo Ooni, òun náà si dáa kọja kò sì sí wahala kankan.

Ka Nipa Olori Silekunola

Olori Naomisilekunola

Oríṣun àwòrán, HM. Queen Evang. Silekunola Moronke Naomi Ogunwusi

Ni ọdun 1993 ni wọn bí i tí wọn sọ ọ ni Naomi Olúwa èyí.

Olori Naomi fẹ Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja ll lọdun 2018.

Wọn ni ọmọ kan papọ, Tadenikawo ni ọdun 2020.

Ọmọ Ilu Akure tíì ṣe olú ìlú ìpínlè Ondo ni Olori Naomi.

Níwọ̀n ìgbà tí Ajihinrere Naomi ti ni òun kii ṣe Olori mọ, a jẹ pe Ooni yoo wa Olori miran nìyẹn nitori ipo rẹ kò leè ṣófo.

Ajihinrere naa to tun fi Wòlíì kun àkọlé orúkọ rẹ naa ni oludasilẹ ìjọ En-Heralds to wa ni Akure, Ìpínlẹ̀ Ondo.