Wo ohun tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tuntun fẹ́ dá lárà láti dẹ́kùn òjòjò tó ń ṣe ètò àbò ní Nàìjíríà

Aworan awọn ọga ọlọpaa tẹlẹ nibi ipade wọn nilu Ibadan

Ninu igbiyanju lati dẹkun iwa ọdaran lorilẹede yii, adele ọga agba ileeṣẹ Ọlọpaa, Kayode Egbetokun ti ṣe afihan erongba lati ṣe ifilọlẹ ikọ agbofinro ti ko gberegbe, ‘Special Intervention Squad’ jakejado orilẹede Naijiria.

Egbetokun fi ọrọ naa lede nilu Ibadan n’ibẹrẹ ọsẹ yii lasiko to n dahun ibeere to niiṣe pẹlu iṣoro eto aabo lati ọwọ alaga igbimọ awọn Mogaji nilẹ Ibadan, Asimiyu Ariori saaju ipade apero awọn ọga agba ileeṣẹ Ọlọpaa tẹlẹri to waye fun ọjọ meji gbako.

Ọga agba ileeṣẹ Ọlọpaa naa tẹnu mọ pataki ajọṣepọ Ọlọpaa pẹlu awọn alẹnulọrọ fun aṣeyọri ajọ naa ni awujọ wa.

Egbetokun fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ loju wi pe ikọ agbofinro tuntun naa yoo dẹ ipinlẹ wọn, pẹlu alaye wi pe atungbyẹwo yoo ba bi awọn Ọlọpaa ṣe n ṣiṣẹ si lorilẹede yii.

O ni, “A n ṣe atungbeyẹwo ọna abayọ si iṣoro eto aabo lorilẹede yii pẹlu iran tuntun ti ileeṣẹ Ọlọpaa orilẹede yii ni fun imugbooro iṣẹ wọn.

Gbogbo Kọmisana Ọlọpaa jakejado orilẹede yii ni a ti fun ni idanilẹkọ fun idagbasoke ilana iṣẹ wọn.”

Bakan naa ni Egbetokun fi kun ọrọ rẹ pe bi ẹnikẹni ba ni ikunsinu si Ọlọpaa kankan, ki wọn fi ẹjọ wọn sun awọn ti o tun jẹ ọga fun wọn lẹnu iṣẹ. O ni ilepa ileeṣẹ Ọlọpaa ni lati riidaju wi pe aabo ti o peye wa fun ẹmi ati dukiya.

Ọga ọlọpaa Ẹgbẹtokun bẹ gomina Seyi MAkinde wo ni Ibadan

Aworan awọn ọga ọlọpaa tẹlẹ naa

Ninu ọrọ ti ọga agba ilẹẹṣẹ Ọlọpaa sọ lasiko ti o ṣe abẹwo si ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde, o ni abẹwo naa duro gẹgẹ bi ọna lati dupẹ lọwọ Makinde fun atilẹyin ati ifọwọsọwọpọ pẹlu ileeṣẹ Ọlọpaa n’ipinlẹ Ọyọ.

O parọwa si Makinde lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rere rẹ, pẹlu alaye wi pe iran tuntun ti wọn ni fun imugbooro ileeṣẹ Ọlọpaa orilẹede yii yoo nilọ iranlọwọ gbogbo awọn Gomina.

Gomina Makinde ti igbakeji rẹ, Amofin Bayo Lawal ṣoju fun nibi ipade naa ṣe alaye pe agbekalẹ Ọlọpaa agbegbe si agbegbe ni ọna abayọ. O ni Ọlọpaa ipinlẹ le ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn Ọlọpaa ijọba apapọ lai di ara awọn lọwọ gẹgẹ bi o ṣe wa lode agbaye.

Makinde jẹjẹẹ atilẹyin fun agbekalẹ Ọlọpaa ipinlẹ, pẹlu alaye wi pe anfani to wa ninu agbekalẹ naa pọ ju ibẹru ti awọn eniyan ni lodi sii.

Ipade apero ọlọjọ meji fun awọn ọga agba ileeṣẹ Ọlọpaa tẹlẹri to waye ni gbọngan igbalejo IITA to n bẹ ni opopona Moniya nilu Ibadan lo jẹ agbekalẹ alaga igbimọ awọn ọga agba ileeṣẹ Ọlọpaa to ti ṣiṣẹfẹyinti, Alhaji Aliyu Attah, pẹlu ajọṣepọ alaga ajọ to ṣe akoso ileeṣẹ Ọlọpaa, Dr. Solomon E. Amse.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọnimọẹrọ Ṣeyi Makinde lo ṣe onigbọwọ apero naa.