Ìdí tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Eko ṣe kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu Akin Abayomi, Omotsho àtàwọn 15 míràn fún ipò Kọmisọna

Ọjọgbọn Akin Abayọmi, Gomina Sanwo-Olu, ati Gbenga Ọmọtọshọ

Oríṣun àwòrán, x/facebook

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko lọjọru kọ jalẹ lati fontẹ lu iyansipo awọn Kọmisọna tẹlẹ tí Gomina Babajide Sanwo-Olu fakalẹ fun ayẹwo.

Awọn Kọmisọna tẹlẹ naa ni Gbenga Omotoso, Akin Abayomi ati Sam Egube.

Awọn yooku ni Cecila Dada, Olalere Odusote ati Folashade Adefisayo.

Orukọ awọn wọnyi yii lo wa lara orukọ Kọmisọna tí ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko dapada fun Gomina.

Orukọ awọn wọnyi yii lo wa lara orukọ Kọmisọna tí ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko dapada fun Gomina.

Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Bisola Branco Adekola buwọlu fun awọn akọroyin.

Ida aadọta awọn ti wọn dapada lo ti sisẹ pẹlu Gomina Babajide Sanwo-Olu ni saa to lọ.

Ile Igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko buwọlu Kọmisọna mejilelogun ninu orukọ mọkandinlogoji ti Gomina fi ransẹ.

Tokunbo Waheb, amugbalẹgbẹ Gomina tẹlẹ lori eto ẹkọ ati Dolapo Fasawe wa ninu awọn orukọ ti Ile Igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko buwọlu.

Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Rt Hon Mudashiru Obasa ni igbesẹ ile lo da le lori ayẹwo ti ẹka ile igbimọ aṣofin to n risi ayẹwo sise tí Akọjanu ile, Fatia Mojeeb lewaju rẹ.

Abẹnugan ile wa kan sara si ẹka fun isẹ takuntakun, to si tun rọ awọn Kọmisọna ti ile igbimọ aṣofin buwọlu lati ri daju pe awọn sin araalu ni ilana to ba ofin mu

Obasa wa se ileri pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ko ni jawọ ninu gbigbe igbesẹ ti yoo mu idẹrun ba awọn eeyan ipinlẹ naa.

Kíló ṣelẹ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin nípínlẹ̀ Eko?

Gbongan ile aṣofin ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, lagos state house of assembly

Lasiko ti wọn gbe orukọ wọn kọmiṣọnna naa de ile igbimọ aṣofin ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin, Họnọrẹbu Mudashiru Obasa gbe igbimọ onigun mejila dide lati ṣayẹwo awọn orukọ naa.

Fidio to jade ni Ọjọru safihan bi awọn aṣofin ṣe n dibo lati buwọlu awọn kọmiṣọnna naa boya wọn fẹ abi wọn ko fẹ.

Nigba ti abẹnugan naa pe orukọ awọn ti wọn ni ko si ẹni to dibo fun ẹnikẹni ninu wọn.

Kilo de ti wọn kọ awọn kọmiṣọnna mẹtadinlogun naa?

Ko i tii han si ẹnikẹni idi ti awọn aṣofin naa fi kọ lati gba awọn aṣofin mẹtadinlogun naa.

Bakan naa ni awọn kan n woye pe orukọ ti wọn ro pe yoo wa nibe ko si nibẹ.

Amọ awọn ti wọn buwọlu yoo ṣiṣẹ fun ipinlẹ Eko, ti wọn yoo si fi orukọ wọn ranṣẹ si gomina lati buwọ lu wọn.

Kí ni Gomina sọ?

Gomina Sanwo-olu

Oríṣun àwòrán, lagos state government

Agbẹnusọ fun Gomina Ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle, ThePunch ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ko ti sọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ naa fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, fun idi eyi Gomina ko le ti sọrọ lori igbesẹ naa.

“Awa ko ti gbọ nnkan, ẹnu ẹyin oniroyin ni a ti n gbọ pe nnkan bayi waye

“A n si n duro de Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko lati ba wa sọrọ kí a to fọhun síta.”

Orukọ tí ile buwọlu

  • Layode Ibrahim
  • Mobolaji Ogunlende
  • Dolapo Fasawe
  • Bola Olumegbon
  • Idris Aregbe
  • Abisola Ruth Olusanya
  • Moruf Akinderu Fatai
  • Kayode Bolaji-Roberts
  • Abiola Olowu
  • Toke Benson-Awoyinka
  • Oreoluwa Finnih- Awokoya
  • Yakub Adedayo Alebiosu
  • Lawal Pedro SAN
  • Tunbosun Alake
  • Gbenga Oyerinde
  • Adekunle Olayinka

Orukọ tí ile dapada fun Gomina

  • Folashade Adefisayo
  • Akin Abayomi
  • Yomi Oluyomi
  • Folashade Ambrose
  • Barakat Bakare
  • Gbenga Omotoso
  • Olalere Odusote
  • Rotimi Fashola
  • Cecilia Dada
  • Sam Egube
  • Olalekan Fatodu
  • Solape Hammond
  • Mosopefolu George
  • Aramide Adeyoye
  • Seun Osiyemi
  • Rotimi Ogunwuyi
  • Olumide Oluyinka